Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì Gbádùn Rẹ̀
1 Ọ̀kan lára ohun tó dùn mọ́ni jù ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” ni ìmújáde ìwé Kí Ní Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? A máa tó bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní pẹrẹu nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, pàápàá nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Nítorí náà, ó yẹ ká mọ ìwé tuntun yìí tinú tẹ̀yìn. A sì máa mọ̀ ọ́n, torí, a máa tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti ọ̀sẹ̀ April 17, 2006.
2 Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ á darí àfiyèsí àwọn ará sí àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ló máa wá fi àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ojú ìwé náà darí ìkẹ́kọ̀ọ́. A ó máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe kókó, a ó sì máa jíròrò wọn. Lẹ́yìn tá a bá ti parí orí kọ̀ọ̀kan, a ó máa jíròrò àpótí náà, “Ohun Tí Bíbélì Fí Kọ́ni,” èyí yóò sì ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ náà torí pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpótí yìí ló jẹ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí náà. Á wù ẹ́ láti máa dáhùn níwọ̀n bí ìwé yìí ti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, tó rọrùn, tó sì fani mọ́ra.
3 Àfikún inú ìwé yìí ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí onírúurú kókó ẹ̀kọ́. A ó lè lo ìsọfúnni yìí nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ bá nílò àlàyé sí i lórí kókó kan pàtó. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ó máa jíròrò àwọn ibi pàtó kan nínú àfikún náà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ẹni tó ń kàwé ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ka gbogbo àlàyé tó wà lábẹ́ kókó kan nínú àfikún náà, àmọ́ tó bá jẹ́ àpilẹ̀kọ tó gùn ni, ṣe la máa dá a sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí. Àfikún kì í ní ìbéèrè tá a fi máa jíròrò rẹ̀. Ṣùgbọ́n alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ náà lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwùjọ lè ṣàlàyé táá fa kókó ibẹ̀ yọ.
4 Kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa yá kánmọ́kánmọ́. Àmọ́, a ò retí pé ká máa ṣe é kánmọ́kánmọ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, pàápàá tí òye wọn nípa Bíbélì ò bá tó nǹkan tàbí tí wọn ò bá tiẹ̀ ní in rárá. (Ìṣe 26:28, 29) Nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, a máa ní láti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀ kúnnákúnná, ká ṣàlàyé àwọn àkàwé àtàwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀ bó ṣe yẹ. Nítorí náà, rí i dájú pé ò ń pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó o lè kópa kíkún nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?