Àpẹẹrẹ Olùkọ́ Ńlá Náà Ni Kó O Máa Tẹ̀ Lé Bó O Bá Ń Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni
1. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
1 Ẹ̀kọ́ Jésù tó jẹ́ Olùkọ́ Ńlá Náà, kì í lọ́jú pọ̀, ó sì máa ń ṣe kedere. Káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ bàa lè ronú sóhun tó ń kọ́ wọn, nígbà míì ó kọ́kọ́ máa ń bi wọ́n ní ìbéèrè tó máa jẹ́ kí wọ́n sọ èrò wọn. (Mát. 17:24-27) Orí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. (Mát. 26:31; Máàkù 7:6) Ó máa ń kíyè sára láti má ṣe kọ́ wọn lóhun tó pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan, torí ó mọ̀ pé wọn ò ní yé kẹ́kọ̀ọ́. (Jòh. 16:12) Jésù tún máa ń fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ọmọlẹ́yìn òun gba ohun tóun ń kọ́ wọn gbọ́ àti pé bóyá wọ́n lóye rẹ̀. (Mát. 13:51) Ohun tí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni wà fún ni láti jẹ́ káwa náà lè mọ bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Jésù.
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan?
2 Àwọn Ìbéèrè Tó Wà Níbẹ̀rẹ̀ Orí Kọ̀ọ̀kan: Nígbà tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ nínú orí kan nínú ìwé náà, ó yẹ kó o ka àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ àkòrí náà sétígbọ̀ọ́ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bi í láwọn ìbéèrè náà lọ́nà tó máa múra ọkàn ẹ̀ sílẹ̀ fún ohun tó fẹ́ kọ́. Tàbí kẹ̀, o lè ní kó sọ èrò rẹ̀ ní ṣókí lórí àwọn ìbéèrè náà. Kò sídìí láti ṣàgbéyẹ̀wò ìdáhùn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́sẹẹsẹ tàbí kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe gbogbo èyí tó kù díẹ̀ káàtó nínú ìdáhùn rẹ̀. O kàn lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fún bó ṣe sọ òye tó ní nípa rẹ̀ kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ìdáhùn rẹ̀ sáwọn ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà lábẹ́ àkòrí náà á jẹ́ kó o lè mọ àwọn ibi tó o ní láti tẹnu mọ́ fún un nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
3. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yéni yékéyéké?
3 Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́: Ìwé Mímọ́ lẹ gbọ́dọ̀ gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kà látòkèdélẹ̀. (Héb. 4:12) Síbẹ̀ náà, kò ní pọn dandan kẹ́ ẹ ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Tẹnu mọ́ àwọn tá a bá lè fi ti ẹ̀kọ́ tá a gbà gbọ́ lẹ́yìn. Àwọn ẹsẹ tó bá kàn tànmọ́lẹ̀ sí àwọn àlàyé náà lè má fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan. Ọ̀nà tí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni gbà ṣàlàyé òtítọ́ ò lọ́jú pọ̀. Rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yéni yékéyéké. Àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ ni kó o tẹnu mọ́, má sì ṣe sọ̀rọ̀ tó pọ̀ tàbí kó o wá máa lọ mú àwọn àlàyé kan tí ò sí nínú ìwé náà tí ò sì pọn dandan wọnú rẹ̀.
4. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ká jíròrò àfikún nígbà tá a bá ń jíròrò orí tá a so ó mọ́?
4 Àfikún: Kókó mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àfikún tó wà nínú ìwé náà dá lé, ó sì jẹ́ láti fi ṣàlàyé síwájú sí i. Kì í ṣe dandan láti jíròrò àwọn kókó náà nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Àwọn àfikún kan wà tó o kàn lè gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó kà fúnra rẹ̀ pàápàá bí àkòrí tá a so àfikún náà mọ́ bá yé e tó sì gba àwọn àlàyé náà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti gbà pé Jésù ni Mèsáyà, ó lè má pọn dandan pé kẹ́ ẹ jíròrò àkòrí tá a pè ní “Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí” èyí tá a so mọ́ orí 4, lábẹ́ àkòrí náà “Ta Ni Jésù Kristi?” Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ohun tó máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní jù ni pé kẹ́ ẹ jíròrò àfikún náà tàbí apá kan lára àfikún náà.
5. Bá a bá wá pinnu láti jíròrò àfikún náà, ọ̀nà wo la lè gbà ṣe é?
5 Bó o bá pinnu láti jíròrò àfikún, o lè ti múra àwọn ìbéèrè tó o máa bi í ní ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, bí ìgbà tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò orí náà fúnra rẹ̀. Bó o bá sì rí i pé ohun tó máa ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni pé kẹ́ ẹ lo àkókò díẹ̀ láti ṣàtúnyẹ̀wò àfikún náà kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tó parí, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó lóye àfikún náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ló kà á láyè ara ẹ̀.
6. Ọ̀nà wo la lè gbà lo àpótí àtúnyẹ̀wò níparí ìkẹ́kọ̀ọ́ orí kọ̀ọ̀kan?
6 Àpótí Àtúnyẹ̀wò: Àpótí tó wà níparí orí kọ̀ọ̀kan máa ń ní àlàyé tó máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yẹn. O lè lo àwọn àlàyé náà láti fi jíròrò àwọn kókó pàtàkì tí orí náà dá lé. Ńṣe làwọn akéde kan máa ń ka àlàyé àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ sétígbọ̀ọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà. Wọ́n á wá ní kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàlàyé ṣókí nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe fi hàn pé òótọ́ ni àlàyé yẹn. Èyí máa ń jẹ́ kí olùkọ́ mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ lóye àwọn kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà àti pé bóyá ó gbà pé àwọn àlàyé náà bá àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ mu. Ó sì tún máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ béèyàn ṣe lè fi Bíbélì ṣàlàyé òtítọ́ fáwọn ẹlòmíì.
7. Báwo la ṣe le lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́?
7 Títẹ̀lé ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ni ọ̀nà tó dáa jù láti gbà ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ká sì sọ wọn dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ láti kọ́ àwọn ẹlòmíì ní òtítọ́ lọ́nà tó ṣe kedere, tó ṣe tààrà, kó sì gbádùn mọ́ni.