Máa Lo Àwọn Ohun Pàtàkì Tó Wà Nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ṣe ń kọ́ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an, tó sì ń fi ohun tó ń kọ́ sílò ni yóò máa dàgbà sí i nípa tẹ̀mí táá sì máa so èso tẹ̀mí. (Sm. 1:1-3) A lè fi àwọn ohun pàtàkì tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú.
Àwọn Ìbéèrè Tó Wà Níbẹ̀rẹ̀ Orí Kọ̀ọ̀kan: Ní ìbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan, àwọn ìbéèrè tí ìdáhùn wọn wà nínú orí yẹn máa ń wà níbẹ̀. O lè bi akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ láwọn ìbéèrè yìí lọ́nà táá jẹ́ kó máa fojú sọ́nà fún ohun tó fẹ́ kọ́. O sì lè sọ pé kó dáhùn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè náà ní ṣókí. Tí ìdáhùn rẹ̀ bá kù díẹ̀ káàtó, má ṣe ṣàtúnṣe rẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Ohun tó bá sọ lo máa fi mọ ibi tí wàá pàfiyèsí sí tàbí tí wàá tẹnu mọ́ bí ẹ ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.—Òwe 16:23; 18:13.
Àfikún: Bí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ kọ́ ní orí náà bá yé e dáadáa, tó sì fara mọ́ ẹ̀kọ́ tó kọ́, o lè gbà á níyànjú pé kó lọ ṣàyẹ̀wò àfikún àlàyé tó wà nínú orí náà láàyè ara rẹ̀. Nígbà míì tó o bá fẹ́ bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ lè kọ́kọ́ fi ìṣẹ́jú díẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí àfikún àlàyé tó kà kó o lè mọ̀ bóyá ó yé e. Àmọ́ tó o bá rí i pé ó máa ṣe é láǹfààní, ẹ lè jọ jíròrò gbogbo àfikún àlàyé náà tàbí apá kan lára rẹ̀. Ẹ lè ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà níbẹ̀, kí o sì bi í láwọn ìbéèrè tó o ti múra sílẹ̀.
Àpótí Àtúnyẹ̀wò: Àpótí àtúnyẹ̀wò tó wà ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan máa ń ní àlàyé tó dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ orí náà. O lè lo apá yìí láti fi rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lóye ẹ̀kọ́ tó kọ́, ó sì lè ṣàlàyé àwọn kókó inú ẹ̀kọ́ náà. Ka àlàyé náà sókè lọ́kọ̀ọ̀kan sétígbọ̀ọ́ akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣàlàyé bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ ṣe fi hàn pé òótọ́ ni àlàyé yẹn.—Ìṣe 17:2, 3.