Apá Kẹrin: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bí A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Wa Láti Máa Múra Sílẹ̀
1 Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń ka ibi tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, tó ń sàmì sí ìdáhùn, tó sì mọ bí òun ṣe lè dáhùn ìbéèrè látọkànwá máa ń tètè tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti fìdí múlẹ̀, kí ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà jọ múra ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ láti lè kọ́ ọ ní bó ṣe lè máa múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ohun tó máa ṣe ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láǹfààní jù ni pé, kẹ́ ẹ jọ múra àkòrí kan sílẹ̀ látòkèdélẹ̀ nínú ìwé tẹ́ ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́.
2 Sísàmì sí Ìdáhùn àti Kíkọ Kókó Ọ̀rọ̀ sí Etí Ìwé: Ṣàlàyé bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè mọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó dáhùn ìbéèrè inú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà. Fi ìwé tìrẹ hàn án, kó lè rí bó o ṣe sàmì sí kìkì àwọn kókó ọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn tó ṣe pàtàkì. Bí ẹ ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ó lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tìrẹ, kí òun náà máa sàmì sí kìkì àwọn ohun tó lè jẹ́ kó rántí ìdáhùn. (Lúùkù 6:40) Lẹ́yìn èyí, sọ pé kó máa dáhùn ìbéèrè látọkànwá, láìsí pé ó ń kà á jáde látinú ìwé. Èyí á jẹ́ kó o lè mọ bí ohun tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ṣe yé e tó.
3 Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó máa fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a kàn tọ́ka sí láìkọ ọ̀rọ̀ wọn. (Ìṣe 17:11) Sọ bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ò kọ ọ̀rọ̀ wọn sínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe ti àwọn kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ lẹ́yìn. Ṣàlàyé bó ṣe lè máa kọ kókó ọ̀rọ̀ sí etí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Máa fi yé e nígbà gbogbo pé inú Bíbélì ni gbogbo ohun tó ń kọ́ ti wá. Rọ akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, tó bá ń dáhùn ìbéèrè kó máa fi ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ò kọ ọ̀rọ̀ wọn sínú ìwé kún àlàyé rẹ̀.
4 Yíyẹ Ibi Tí Ẹ Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Wò àti Ṣíṣe Àtúnyẹ̀wò: Tí akẹ́kọ̀ọ́ bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó máa dára kó kọ́kọ́ yẹ ibi tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ wò látòkèdélẹ̀. Sọ fún un pé tó bá fẹ́ ṣe èyí, ó kàn lè wo àkòrí ẹ̀kọ́ náà, àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn àwòrán tó wà níbẹ̀. Ṣàlàyé fún un pé kó tó parí ìmúrasílẹ̀ rẹ̀, ó yẹ kó tún ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà, bóyá kó lo àpótí àtúnyẹ̀wò, bó bá wà nínú ẹ̀kọ́ náà. Tó bá ń ṣe àtúnyẹ̀wò bẹ́ẹ̀, á lè máa rántí ẹ̀kọ́ náà.
5 Bí a bá kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ dáadáa, á lè máa dáhùn ní ìpàdé ìjọ, ìdáhùn rẹ̀ á sì dára gan-an. Yóò tún jẹ́ kó mọ bó ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ fúnra rẹ̀, èyí tó máa ṣe é láǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ lẹ́yìn ìgbà tó bá kẹ́kọ̀ọ́ tán.