Apá Kejì: Bí A Ṣe Lè Darí Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Mímúrasílẹ̀ Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́
1 Bá a bá fẹ́ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ò kàn ní sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ká kàn ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí níbẹ̀ nìkan. Ó yẹ ká ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ibẹ̀ lọ́nà táá fi wọ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn. Èyí gba pé ká múra sílẹ̀ dáadáa, ká sì máa ronú nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà bá a ṣe ń múra sílẹ̀.—Òwe 15:28.
2 Bí A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbàdúrà sí Jèhófà nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà àtàwọn ohun tó lè mú kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Kól. 1:9, 10) Láti lè lóye kókó pàtàkì ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ yékéyéké, kọ́kọ́ ronú lórí àkọlé ẹ̀kọ́ náà, àwọn ìsọ̀rí inú rẹ̀ àti àwòrán èyíkéyìí tó bá wà níbẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Ẹ̀kọ́ wo ni ibi tí mo kà yìí ń kọ́ni?’ Èyí á jẹ́ kó o lè tẹnu mọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ ibẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
3 Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà láti ìpínrọ̀ dé ìpínrọ̀. Rí i pé o mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tó jẹ́ kókó pàtàkì nìkan. Ronú nípa bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí ṣe bá kókó pàtàkì inú ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan mu, kó o sì wo èyí tó o máa kà lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ó dára tó o bá lè kọ àwọn kókó pàtàkì inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sétí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ. Ó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ rí i ní kedere pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ohun tí òun ń kọ́ ti wá.—1 Tẹs. 2:13.
4 Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Bá Ipò Akẹ́kọ̀ọ́ Mu: Lẹ́yìn náà, bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ náà, máa kíyè sí àwọn ohun tó lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Gbìyànjú láti ronú àwọn ìbéèrè tó lè béèrè àtàwọn kókó tó lè ṣòro fún un láti lóye tàbí láti gbà. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ló yẹ kó mọ̀ tàbí tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lé lórí kó bàa lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Báwo ni mo ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ mi wọ̀ ọ́ lọ́kàn?’ Rí i pé o fi àwọn nǹkan wọ̀nyí sọ́kàn tẹ́ ẹ bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà míì, o lè rí i pé ó yẹ kó o wá àkàwé kan tàbí àlàyé kan sílẹ̀, tàbí àwọn ìbéèrè kan tó o máa lò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè lóye ìtumọ̀ kókó kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. (Neh. 8:8) Àmọ́ o, má ṣe máa mú àfikún àlàyé tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan wọnú ẹ̀kọ́ náà. Ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ṣókí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ kó lè rántí àwọn kókó inú ẹ̀kọ́ náà.
5 Inú wa máa ń dùn gan-an táwọn ẹni tuntun bá ń so èso òdodo, èyí tó máa fi ìyìn fún Jèhófà! (Fílí. 1:11) Kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, máa múra sílẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà tó o bá fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.