Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 9
Orin 57
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Bí àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, ẹ lò wọ́n láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ August 15 àti Jí! September 8 lọni. (Àbá kẹta ni kó o lò láti fi Jí! September 8 lọni.) A tún lè lo àwọn ọ̀nà mìíràn láti fi ìwé ìròyìn lọni. Sọ fún onílé nípa ètò ọrẹ ṣíṣe. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n mú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè wá sí ìpàdé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.
15 min: “Ìfaradà Lérè.”a Fi àlàyé díẹ̀ kún un látinú Ilé Ìṣọ́ December 15, 2000, ojú ìwé 22 àti 23, ìpínrọ̀ 15 sí 18.
20 min: Fífi Ìwé Ìléwọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 2002, ojú ìwé 3 àti 4. Ṣàlàyé pé a múra tán láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ bí ipò wọn bá ṣe gbà, bí ìpínrọ̀ 5 ṣe sọ. Fi àṣefihàn kan tàbí méjì kún un, tá a gbé ka ìpínrọ̀ 8 sí 10. Àmọ́, bí ọ̀nà mìíràn bá wà táwọn ará máa ń gbà fi ìwé lọni ní ìpínlẹ̀ ìjọ tí èyí sì ń méso jáde, ìyẹn ni kó o ṣàlàyé dípò èyí tá a dábàá, kó o sì jẹ́ ká ṣe àṣefihàn rẹ̀. Sọ pé kí àwọn ará sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo ìwé ìléwọ́ náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?
Orin 74 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 16
Orin 189
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù August sílẹ̀.
15 min: Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 55 sí 59. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà mẹ́rin táwọn òbí lè gbà ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò.
20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kejì.”b Fi àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún kún un. Akéde kan bi alàgbà kan nípa bí òun ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Alàgbà náà sọ pé ohun tó máa ń sábà jẹ́ ìṣòro ni pé àwọn kan máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ láti fi sọ̀rọ̀ lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì àtàwọn àlàyé tí kò pọn dandan nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó lo ẹ̀kọ́ 9 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti jẹ́ kí akéde náà mọ bá a ṣe lè (1) gbájú mọ́ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà, (2) lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí lọ́nà tó múná dóko, àti bá a ṣe lè (3) mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ipò akẹ́kọ̀ọ́ náà mu. Alàgbà náà sọ pé ó yẹ ká máa múra sílẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́.
Orin 85 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 23
Orin 33
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! September 8 lọni. (Àbá kẹrin ni kó o lò láti fi Jí! September 8 lọni.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, jẹ́ káwọn ará rí bá a ṣe lè wàásù fún olùkọ́.
20 min: Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Sún Mọ́ Jèhófà. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa fi lọni lóṣù September. Sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà ní ojú ìwé 3, ìyẹn ọ̀rọ̀ tá a kọ sí òǹkàwé, kó o sì mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìsọ̀rí mẹ́rin inú ìwé náà ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Jèhófà ní. Nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, orí kan máa ń wà tó sọ bí Jésù ṣe fi ànímọ́ náà ṣèwà hù, bákan náà ni orí mìíràn á tún ṣàlàyé bí àwa náà ṣe lè fi ànímọ́ náà ṣèwà hù. Àwòrán ìtàn inú Bíbélì mẹ́tàdínlógún ló wà nínú ìwé yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ sì gba odindi ojú ewé kan. Àpótí tó ní àkọlé náà “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò” á mú ká lè ronú lórí àwọn ohun pàtàkì mìíràn nípa ẹ̀kọ́ tá a kọ́. Sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà “Àbá Nípa Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà Lọni” tó wà ní ojú ìwé 2 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2004, kó o sì ṣètò pé kí akéde tó dáńgájíá kan ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìfilọni náà.
10 min: Àwọn ìrírí táwọn akéde ní. Sọ pé káwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ wa nínú oṣù yìí. Ǹjẹ́ a ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyíkéyìí? Bá a bá ti bẹ̀rẹ̀, sọ ìrírí tí akéde kan tàbí méjì ní, tàbí kó o ṣètò pé ká ṣe àṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú ìrírí náà.
Orin 124 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 30
Orin 90
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù August sílẹ̀.
15 min: Bí A Ṣe Lè Yanjú Èdèkòyédè. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 139 sí 145. Ran àwùjọ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wọn tó bá dọ̀ràn yíyanjú èdèkòyédè tó wà láàárín àwọn àtàwọn ará mìíràn. Bó bá jẹ́ ìbanilórúkọjẹ́ tàbí ìluni-ní-jìbìtì ni ìṣòro náà, kí àwọn tí ọ̀ràn kàn bójú tó o nípa títẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ tó wà ní Mátíù 18:15-16. Ìgbà tí ọ̀ràn náà ò bá yanjú lẹ́yìn gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ni kí wọ́n tó fi lọ àwọn alàgbà. (Tún wo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 147, ìpínrọ̀ 9.)
20 min: Ǹjẹ́ Ó Ti Ṣe Ọ́ Láǹfààní? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí a sọ̀rọ̀ lórí àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí, tí wọ́n wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá: Kọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ lò sórí ìwé pélébé kan. (km-YR 10/03 ojú ìwé 1) Gbóríyìn fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kó o yìn wọ́n lórí ohun pàtó kan tí wọ́n ṣe, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ti inú ọkàn wá. (km-YR 11/03 ojú ìwé 1) Lọ wàásù nígbà tó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nílé. (km-YR 12/03 ojú ìwé 1) Ṣètò àkókò pàtó fún Bíbélì kíkà, mímúra sílẹ̀ fún ìpàdé àti jíjáde òde ẹ̀rí. (km-YR 1/04 ojú ìwé 4) Máa lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tó o bá ń ka Bíbélì. (km-YR 3/04 ojú ìwé 2) Pinnu pé wàá ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. (km-YR 4/04 ojú ìwé 1) Máa wàásù ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé. (km-YR 7/04 ojú ìwé 4) Máa fi ìwé ìléwọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (km-YR 8/04 ojú ìwé 2) Sọ pé kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí látinú fífi àwọn àbá wọ̀nyí sílò.
Orin 145 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 6
Orin 197
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
25 min: “Ẹ Ní Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà.”c Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá aṣáájú ọ̀nà kan tàbí méjì lẹ́nu wò. Ní kí wọ́n sọ bí àpẹẹrẹ àwọn òbí, àwọn alàgbà tàbí ti àwọn ẹlòmíràn ṣe fún wọn níṣìírí láti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Orin 142 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.