Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
1 Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ April 17, ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! la óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ọ̀pọ̀ ló ti ka ìwé fífani-lọ́kàn-mọ́ra yìí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, a láǹfààní láti gbádùn àwọn àǹfààní tí yóò wá láti inú jíjíròrò rẹ̀ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Gbogbo akéde, àwọn olùfìfẹ́hàn, àti ọmọdé la ń ké sí, a ń rọ̀ yín gidigidi láti máa wá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ìwé Bíbélì tí a ń pè ní Dáníẹ́lì.—Diu. 31:12, 13.
2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Ìtọ́ni: A ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì lódindi sínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Rí i dájú pé o fi ẹ̀dà kan pa mọ́ sínú ìwé rẹ. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi orí àti ìpínrọ̀ tí a óò kà nínú ìwé náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ hàn, ó tún fi àwọn ẹsẹ tí a óò jíròrò láti inú ìwé Dáníẹ́lì hàn. Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ń ṣàlàyé bí a óò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ibì kan nínú ìwé náà àti ìgbà tí a óò kẹ́kọ̀ọ́ wọn. Bí a bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ọ̀sẹ̀ kan, a rọ Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti ṣàtúnyẹ̀wò pẹ̀lú àwùjọ nínú àwọn ẹsẹ pàtó láti inú ìwé Dáníẹ́lì tí a kọ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ọ̀sẹ̀ yẹn. Bí àkókò bá ṣe wà tó, a lè ka àwọn ẹsẹ náà, kí a sì ṣàlàyé wọn. Ó lè gba ọ̀sẹ̀ méjì ká tó lè jíròrò àwọn ẹsẹ kan tán nítorí pé jíjíròrò bí a ṣe lè fi wọ́n sílò lè ní í ṣe pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ọ̀sẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e.
3 Múra fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tó Jinlẹ̀: A ti ṣètò láti rí i dájú pé lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a óò fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ibi tí a yàn nítorí pé a óò ní àkókò tó pọ̀ tó. Ẹ̀kọ́ mẹ́rin ò tó nǹkan. Nítorí náà, lópin ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sẹ̀ June 5, Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè fi ṣíṣàtúnyẹ̀wò Dáníẹ́lì 2:1-40 kún un. Ní ọ̀sẹ̀ June 26, ó lè ṣàtúnyẹ̀wò Dáníẹ́lì 3:1-30. Ní ọ̀sẹ̀ September 4, kí a jíròrò dáadáa nípa àwòrán àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lójú ìwé 139. Kí a jíròrò nípa ṣáàtì tó wà lójú ìwé 188 àti 189 ní ọ̀sẹ̀ October 2.
4 Múra sílẹ̀ dáadáa fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí o sì máa kópa nínú rẹ̀. Máa mọrírì àǹfààní tí o ní pé o wà nínú ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí, àti láti máa jàǹfààní láti inú ìlàlóye àti ìmọ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ ń pèsè. (Dán. 12:3, 4) Fi inú rere fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti máa wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ déédéé. Kí gbogbo wa máa fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run bí a ṣe fi hàn nínú ìwé Dáníẹ́lì tí ń múni ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.—Héb. 10:23-25; 2 Pét. 1:19.