‘Ta Ni Yóò Lọ fún Wa?’
Nígbà tí Jèhófà gbé ìbéèrè yí dìde, Aísáyà dáhùn lọ́gán pé: ‘Èmi nìyí! Rán mi.’ (Aísá. 6:8) Nítorí pé ìkórè náà pọ̀ lónìí, a ń ṣe ìkésíni kan náà nísinsìnyí. A nílò ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún—àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé—ní kánjúkánjú! (Mát. 9:37) O ha ṣe tán láti yọ̀ǹda ara rẹ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, September 1, ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn ti ọdún 1998, yóò jẹ́ àkókò tí ó dára láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Èé ṣe tí ìwọ kò fi béèrè ìwé ìforúkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà?