ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/09 ojú ìwé 1
  • Ṣó O Lè Ṣe Púpọ̀ sí I Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Lè Ṣe Púpọ̀ sí I Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà—Ǹjẹ́ O Lè Ṣe É?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 7/09 ojú ìwé 1

Ṣó O Lè Ṣe Púpọ̀ sí I Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù?

1. Kí lohun tó jẹ́ kánjúkánjú fún wa láti ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù, kí sì nìdí?

1 Nígbà tí Jésù rí bí ogunlọ́gọ̀ èèyàn ṣe fìfẹ́ hàn sí gbígbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n “bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”(Mát. 9:37, 38) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé apá tó kẹ́yìn nínú ìgbà ìkórè la wà yìí, iṣẹ́ wa jẹ́ kánjúkánjú ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Èyí tó túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ fi bá a ṣe lè túbọ̀ máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù sínú àdúrà wa.—Jòhánù 14:13, 14.

2. Kí làwọn kan ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìtọ́ni Jésù pé kí wọ́n bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú pápá?

2 Bá A Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ sí I: Bí Jèhófà ṣe ń darí wa tó sì ń ràn wá lọ́wọ́, ó ti ṣeé ṣe fáwọn tó pọ̀ lára wa láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. (Sáàmù 26:2, 3; Fílí. 4:6) Àwọn kan ti sapá gidigidi láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dún. Èyí ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ayọ̀ tí wọ́n rí nínú ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sì ti mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé.—Ìṣe 20:35.

3. Bó o bá ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí, kí lo máa fẹ́ láti ṣe báyìí?

3 Ṣó O Lè Pa Dà Sẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?: Bó o bá ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí, ó dájú pé o ò jẹ́ gbàgbé bí iṣẹ́ náà ti lárinrin tó. Ṣó o ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ náà? Ó ṣeé ṣe kó o ti rí ojútùú sóhun tó mú kó o fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Bóyá àkókò nìyí fún ẹ láti gbádùn àǹfààní àkànṣe yìí lẹ́ẹ̀kan sí i.—1 Jòhánù 5:14, 15.

4. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ló ṣí sílẹ̀ fún gbogbo wa?

4 Iṣẹ́ ìkórè náà ṣì ń bá a nìṣó, kò sì ní pẹ́ parí. (Jòhánù 4:35, 36) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣàgbéyẹ̀wò bí ipò nǹkan ṣe rí fún wa ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ká lè mọ̀ bóyá á ṣeé ṣe fún wa láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bó bá sì jẹ́ pé lóòótọ́ la ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ǹjẹ́ a lè wá ọ̀nà míì tá a lè gbà já fáfá sí i gẹ́gẹ́ bí akéde? (Máàkù 12:41-44) Àǹfààní ńlá ló ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tí àyè bá yọ fún láti jẹ́ kí Jèhófà lò wọ́n nínú iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí!—Sáàmù 110:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́