Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí fún ₦15: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? September: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. October: Àsansílẹ̀ owó fún yálà Jí! tàbí Ilé Ìṣọ́ tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. Bẹ̀rẹ̀ láti apá ìparí oṣù náà, a óò pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Kingdom News No. 35 káàkiri. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí, yàtọ̀ sí Kingdom News No. 35 tí a óò kó ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àkókò tí ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò yóò máa sọ ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Agbára Jèhófà Tí Ń gbani Là.”