“Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn” Ń Fi Tinútinú Bójú Tó Agbo Ọlọ́run
1 Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ mà dára o, ní ti pé ó fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”! (Éfé. 4:8, 11, 12) Wọ́n ń bójú tó ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́, títí kan ṣíṣàbójútó agbo Ọlọ́run tinútinú. (1 Pét. 5:2, 3) Gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú ìṣètò yìí, torí pé a nílò rẹ̀ gan-an. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí ní ìfẹ́ àtọkànwá sí ire tẹ̀mí gbogbo ìjọ. Wọ́n ń dàníyàn nípa àwọn tó ń dojú kọ ìṣòro, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, àwọn tó ní àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó kan tàbí àwọn tó ti ṣáko lọ.—Fílí. 2:4; 1 Tẹs. 5:12-14.
2 Nígbà tí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé bá kó jìnnìjìnnì bá wa, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí máa ń fi hàn pé àwọn “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” Nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú wa, tó sì ń ṣe wá bíi pé ká rẹ́ni tó máa bá wa sọ̀rọ̀ ìtùnú, wọ́n máa ń tù wá lára, “bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi” tàbí “bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.”—Aísá. 32:2.
3 Fífún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí: Àwọn alàgbà máa ń sapá lákànṣe láti fún àwọn tí kò ṣe déédéé àti àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ níṣìírí, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n tún lè máa kópa déédéé nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìjọ. Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí débi pé wọ́n tún ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Gbogbo báwọn alàgbà ṣe ń sapá lọ́nà yìí ń ṣàfihàn àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà fún wa, ó sì ń fi hàn pé Jésù Kristi ló ń darí wọn. Jésù fi irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ ní ti pé ó bìkítà fún èyíkéyìí nínú àwọn àgùntàn rẹ̀ tó bá ṣáko lọ tàbí tó sọ nù.—Mát. 18:12-14; Jòh. 10:16, 27-29.
4 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí, tí wọ́n wà lábẹ́ ìdarí Jésù máa ń fojú sílẹ̀ láti rí àwọn àmì tó lè fi hàn bóyá ẹnì kan ti ń dẹwọ́ nípa tẹ̀mí. Bó bá dà bíi pé ẹnì kan ń rẹ̀wẹ̀sì, tàbí tí kì í wá sí ìpàdé déédéé mọ́, tàbí tí kò mú iṣẹ́ ìwàásù ní ọ̀kúnkúndùn mọ́, ó ṣeé ṣe kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Àwọn alàgbà múra tán láti ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń fi ẹ̀mí ayé hàn nínú ìwọṣọ àti nínú ìmúra rẹ̀, tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe lámèyítọ́ àwọn ará nínú ìjọ. Nítorí ojúlówó ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí wọ́n ní fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, àwọn alábòójútó tó bìkítà ń fi tinútinú ‘fún wọn ní ọkàn àwọn fúnra wọn,’ láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí iná ìfẹ́ tí àwọn wọ̀nyí ní fún Jèhófà lè máa jó.—1 Tẹs. 2:8.
5 Nígbà kan sẹ́yìn, àwọn Kristẹni kan tó ti ṣèyàsímímọ́ ti sọ ara wọn di ẹni tí kì í ṣe apá kan ìjọ Ọlọ́run mọ́. Èyí mú kí wọ́n di aláìṣiṣẹ́mọ́ nípa tẹ̀mí nítorí ìṣòro àìsàn, ti ìṣúnná owó tàbí ti ìdílé tó ń mu wọ́n lómi. Àwọn ará kan ti ṣí lọ sí àgbègbè tuntun, wọn kò sì gbìyànjú láti wá ìjọ tó wà nítòsí ibẹ̀. Kàkà kí àwọn alàgbà máa ṣe lámèyítọ́, ńṣe ni wọ́n máa ń fi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ fi àwọn ará lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà bìkítà fún àwọn àgùntàn rẹ̀, àti pé yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. (Sm. 55:22; 1 Pét. 5:7) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò lè ran agbo lọ́wọ́ láti mọ̀ pé bí wọ́n bá ‘sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sún mọ́ wọn,’ yóò sì fún wọn ní ìtùnú àti ìtura.—Ják. 4:8; Sm. 23:3, 4.
6 Mímọrírì Akitiyan Àwọn Aláìlera: Àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyí tún máa ń dàníyàn nípa àwọn téèyàn lè fẹ́ máa fojú pa rẹ́. Nínú gbogbo ìjọ làwọn kan tó jẹ́ aláìlera wà, bóyá tí wọn kò lè jáde kúrò nínú ilé wọn tàbí tí wọ́n ń sapá láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ lọ́nà kan ṣá. Ipò tí wọ́n wà kò lè jẹ́ kí wọ́n máa polongo ìhìn rere Ìjọba náà ní kíkún. Ó lè jẹ́ pé kìkì ìgbà tí wọ́n ń ráyè wàásù ni ìgbà tí àwọn àlejò bá lọ bẹ̀ wọ́n wò, tàbí tí wọ́n bá ń jẹ́rìí fún àwọn èèyàn tó ń kọjá lọ tàbí àwọn tó ń tọ́jú wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń kópa tó jọjú pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí agbára wọ́n gbé láti ṣe, nítorí pé wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù tí gbogbo wa ń ṣe. (Mát. 25:15) Kódà, bó bá jẹ́ pé ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ni wọ́n fi wàásù, a ní láti ròyìn rẹ̀, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ akéde Ìjọba náà tó ń ṣe déédéé.
7 “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí mọ àwọn nǹkan tẹ̀mí tí àwọn arákùnrin wọn nílò, pàápàá lásìkò tá a wà yìí nínú ọdún, ìyẹn sáà Ìṣe Ìrántí. Àkókò yìí mà kúkú ṣe rẹ́gí gan-an o fún àwọn alàgbà láti sapá lákànṣe kí wọ́n lè ran gbogbo àwọn tó ti ṣáko lọ lọ́wọ́! Ìrànwọ́ yìí á mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tó máa ń jẹ yọ látinú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà pẹ̀lú ìjọ. Inú wa máa ń dùn tá a bá rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” tí wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ, tí wọ́n sì ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti túbọ̀ fìdí ìgbàgbọ́ wọn múlẹ̀ nínú ẹbọ ìràpadà náà.—Gál. 6:10; Lúùkù 15:4-7; Jòh. 10:11, 14.