Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, Iṣẹ́ Tí Ń Gbẹ̀mí Là Ni!
1 Òun ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lákòókò tá a wà yìí. Òun ni Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi, àti ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì darí àfiyèsí sí. Kí ni nǹkan náà, èé sì ti ṣe tó fi ṣe pàtàkì? Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn là ni!—Róòmù 1:16; 10:13, 14.
2 Àwọn èèyàn kan lè rò pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọ́n jẹ́ nípa gbígbìyànjú láti mú kí ipò ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i fún tẹrú tọmọ. Ohun tó gba ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn ni akitiyan láti mú kí àlàáfíà wà, láti gbógun ti àìsàn, àti láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé tó ń jó rẹ̀yìn gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ṣùgbọ́n kí ló lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní jù lọ?
3 Iṣẹ́ Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an: Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló ṣàlàyé ìdí tá a fi wà láàyè, ohun tó fa ìjìyà àwa ẹ̀dá ènìyàn, àti ìrètí kan ṣoṣo tó ṣeé fọkàn tẹ̀ fún ọjọ́ iwájú. Ìhìn rere náà ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kí wọ́n bàa lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílí. 4:7) Ìhìn rere Ìjọba yìí nìkan ló lè fún àwọn èèyàn ní ìtọ́sọ́nà gúnmọ́ láti lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé pẹ̀lú àṣeyọrí, ó sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè yè bọ́ nígbà tá a bá pa ayé búburú yìí run lọ́jọ́ iwájú. (1 Jòh. 2:17) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí sún wa láti sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà?
4 Fún àpẹẹrẹ: Ọ̀nà wo ló máa dára jù lọ láti gbà ṣèrànwọ́ fún àwọn ará abúlé kan tí gbogbo wọn ti sùn lọ fọnfọn, àmọ́ tí ìsédò wọn ti fẹ́ ya lulẹ̀, tí alagbalúgbú omi sì ti fẹ́ ya bò wọ́n mọ́lẹ̀? Ṣé gbígbọ́n lára omi tó wà lẹ́yìn ìsédò tó máa tó wó lulẹ̀ náà ni? Àbí fífi àwọn ohun ẹlẹ́wà ṣe ọ̀ṣọ́ sí abúlé tó máa tó pa rẹ́ náà? Rárá o! Àfi ká tètè jí àwọn ará abúlé náà lójú oorun, ká kìlọ̀ fún wọn nípa àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ká sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sá àsálà! Inú ewu ńlá làwọn tó wà lójú oorun nípa tẹ̀mí lónìí wà. (Lúùkù 21:34-36) Níwọ̀n bí ètò àwọn nǹkan yìí yóò ti kógbá sílé láìpẹ́ jọjọ, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti máa wàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú fún gbogbo àwọn ẹni tó bá ṣeé ṣe fún wa láti wàásù fún!—2 Tím. 4:2; 2 Pét. 3:11, 12.
5 Máa Bá Iṣẹ́ Yìí Nìṣó: Ẹ jẹ́ ká wá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi wàásù ìhìn rere náà fún àwọn olóòótọ́ inú púpọ̀ sí i—nínú ilé wọn, lójú pópó, lórí tẹlifóònù àti láwọn ọ̀nà mìíràn yàtọ̀ sí ìwàásù láti ilé dé ilé. Iṣẹ́ tí Jèhófà fún wa láti ṣe ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo iṣẹ́ tá a lè dáwọ́ lé. Bá a bá ṣe é tìtaratìtara, a ó lè ‘gba ara wa àti àwọn tí ń fetí sí wa là.’—1 Tím. 4:16.