Fífúnrúgbìn Yanturu Máa Ń Mú Ìbùkún Jìngbìnnì Wá
1 Gbogbo wa là ń wọ̀nà fún ìmúṣẹ àwọn ìlérí kíkọyọyọ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àní nísinsìnyí pàápàá, Jèhófà ń rọ̀jò ọ̀pọ̀ ìbùkún sórí wa kí ìgbésí ayé wa bàa lè túbọ̀ lárinrin. Bá a bá ṣe ṣakitiyan tó la ṣe máa jàǹfààní tó lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, “ẹni tí ó bá . . . ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú.” (2 Kọ́r. 9:6) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tá a lè gbà fi ìlànà yìí sílò.
2 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa: Wíwàásù ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn nígbàkigbà tó bá ti ṣeé ṣe fún wa máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. (Òwe 3:27, 28) Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ń fúnrúgbìn yanturu nípa mímú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn túbọ̀ gbòòrò sí i, èyí kan ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Gbogbo wa lè fúnrúgbìn yanturu nípa sísapá gidigidi láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn àti nípa fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni nígbàkigbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀. (Róòmù 12:11) Sísa gbogbo ipá wa láwọn ọ̀nà wọ̀nyí yóò jẹ́ ká ní àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí, yóò sì jẹ́ ká ní ayọ̀ púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
3 Ṣíṣètìlẹyìn fún Ire Ìjọba Ọlọ́run: Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘fífúnrúgbìn yanturu’ yìí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú fífi àwọn ohun ìní ti ara ṣètọrẹ. (2 Kọ́r. 9:6, 7, 11, 13) Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún ire Ìjọba náà, bóyá nípa lílo ara wa tàbí nípa fífi àwọn ohun ìní wa ṣètọrẹ. A lè ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A tún lè yọ̀ǹda ara wa láti lọ́wọ́ nínú títún àwọn ibi tá a ti ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ ṣe, ká sì rí i pé wọ́n wà ní ipò bíbójúmu. Láfikún sí i, a lè ṣètọrẹ owó fún ìnáwó ìjọ àti fún iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe yíká ayé. Bí gbogbo wa ti ń ṣe ipa tiwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ẹ ò rí i bí inú wa ti ń dùn tó láti rí àwọn ìbùkún yanturu tí Jèhófà ń rọ̀jò rẹ̀ sórí iṣẹ́ tó fàṣẹ sí yìí!—Mál. 3:10; Lúùkù 6:38.
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí [a] múra tán láti ṣe àjọpín.” Bá a ṣe ń kọbi ara sí ìṣílétí yìí, à ń gbádùn àwọn ìbùkún jìngbìnnì nísinsìnyí. Lọ́wọ́ kan náà, à ń “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara [wa] de ẹ̀yìn ọ̀la [àti de] ìyè tòótọ́” tó ń bọ̀.—1 Tím. 6:18, 19.