Jẹ́ Kí Ohun Tó O Ní Tẹ́ Ọ Lọ́rùn
1 Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti pèsè àwọn nǹkan tara tí ìdílé wa nílò fún wọn, àmọ́ kò wá yẹ kó jẹ́ èyí la máa fi ṣe góńgó tá à ń lépa nínú ìgbésí ayé. Àwọn nǹkan tẹ̀mí ló gbọ́dọ̀ gbapò kìíní. (Mát. 6:33; 1 Tím. 5:8) Fífi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú àwọn nǹkan tara jẹ́ ìpèníjà kan láwọn “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí. (2 Tím. 3:1) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì?
2 Jẹ́ Kí Ìlànà Bíbélì Máa Tọ́ Ọ Sọ́nà: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ìlépa ọrọ̀ lè ṣèpalára fún wa nípa tẹ̀mí. (Oníw. 5:10; Mát. 13:22; 1 Tím. 6:9, 10) Níbi tí àkókò dé yìí, yóò jẹ́ ohun eléwu fún èyíkéyìí lára wa bá a bá jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí ọ̀ràn nípa ìṣúnná owó gbà wá lọ́kàn débi pé a óò wá máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, irú bí ìpàdé, ìkẹ́kọ̀ọ́, àti iṣẹ́ ìsìn pápá. (Lúùkù 21:34-36) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tím. 6:7, 8.
3 Èyí ò wá túmọ̀ sí pé káwọn Kristẹni mọ̀ọ́mọ̀ fi ara wọn sínú ipò òṣì o. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn yẹn jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún wa, ìyẹn ni oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé tó dára láti gbé. Bá a bá ti ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé, kó yẹ ká tún máa ṣe kìràkìtà torí àtilè gbé ìgbésí ayé olówó. Nígbà tá a bá ń ronú láti ra nǹkan kan tàbí láti wá àfikún iṣẹ́ kan tó máa túbọ̀ mówó wọlé, ó yẹ ká béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pọn dandan?’ Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn onímìísí yìí sílò, tó sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Héb. 13:5.
4 Bá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, òun yóò ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 3:5, 6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká tó lè ní àwọn ohun kòṣeémánìí ojoojúmọ́, kò yẹ ká wá sọ wọ́n di bàbàrà nínú ìgbésí ayé wa. Ì báà jẹ́ púpọ̀ la ní tàbí ìwọ̀nba, Jèhófà ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé láti tẹ́ àwọn àìní wa lọ́rùn. (Fílí. 4:11-13) Látàrí èyí, a óò gbádùn ìtẹ́lọ́rùn tí Ọlọ́run ń pèsè àtàwọn ìbùkún mìíràn.
5 Fara Wé Ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlòmíràn: Òbí anìkàntọ́mọ kan, ẹni tó ń tọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ọ̀nà òtítọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìgbésí ayé rẹ̀ rọrùn díẹ̀díẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé tó ń gbé tiẹ̀ tù ú lára gan an, ó kó lọ sínú ilé tó kéré jùyẹn lọ, lẹ́yìn ìyẹn ló tún wá kó lọ sí ilé alájùmọ̀gbé. Èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti dín àkókò tó ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù, kó bàa lè ráyè lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ ti dàgbà tó sì ti relé ọkọ, ìyá yìí tètè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tó ń gbà dín kù. Ọdún keje rèé tí arábìnrin wa ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, kò sì kábàámọ̀ kankan nítorí àwọn nǹkan tara tó fi du ara rẹ̀ láti bàa lè fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
6 Alàgbà kan àti aya rẹ̀ ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé fún ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n sì tún ń tọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta lákòókò kan náà. Gbogbo wọn nínú ìdílé náà ti mọ béèyàn ti ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn torí pé kìkì àwọn ohun tí wọ́n nílò ni wọ́n máa ń wá kì í ṣe àwọn ohun tí wọ́n bá kàn ti fẹ́. Arákùnrin náà sọ pé: “A ò walé ayé máyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkókò kan wà táwọn nǹkan nira, ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tá a nílò. . . . Nígbà tí mo bá ń rí bí ìdílé mi ṣe ń fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, mo máa ń ronú pé bó ṣe yẹ kí nǹkan rí gan-an nìyí, inú mi sì máa ń dùn pé à ń ṣàṣeyọrí.” Aya rẹ̀ fi kún un pé: “Nígbà tí mo bá ń rí bí ọwọ́ [ọkọ mi] ṣe dí torí àwọn nǹkan tẹ̀mí, inú mi máa ń dùn gan an ni.” Àwọn ọmọ pàápàá láyọ̀ pé àwọn òbí wọn pinnu láti sin Jèhófà bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
7 Gbogbo àwọn tó ń fi ìfọkànsìn Ọlọ́run ṣáájú ìlépa àwọn nǹkan tara nírú ọ̀nà yìí ni Bíbélì ṣèlérí fún pé, wọn yóò gba ìbùkún yanturu nísinsìnyí àti nínú ayé tí ń bọ̀.—1 Tím. 4:8.