O Lè Di Ọlọ́rọ̀!
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà déédéé?
1 Ṣó ò ń wá bó o ṣe fẹ́ di aláyọ̀ tó o sì fẹ́ ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé rẹ? Ṣé inú ẹ máa ń dùn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ṣé ó sì máa ń tẹ́ ẹ lọ́rùn tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Jèhófà? Bí ìdáhùn rẹ sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó o ronú lórí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ká sòótọ́, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ ká kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò ká tó gbaṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, irú bí ọ̀rọ̀ nípa ìdílé àtàwọn ojúṣe kan tí Ìwé Mímọ́ gbé lé wa lọ́wọ́, ìlera wa, ibi tágbára wa mọ náà ò sì gbẹ́yìn.
2. Mẹ́nu ba díẹ̀ lára ọrọ̀ nípa tẹ̀mí táwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń ní.
2 Lábẹ́ ìmísí, Sólómọ́nì jẹ́ ká mọ̀ pé ìbùkún Jèhófà ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọrọ̀ nípa tara. (Òwe 10:22) Lónìí, olórí ìbùkún tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọrọ̀ nípa tẹ̀mí. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ń gbádùn ìbùkún nípa tẹ̀mí yìí lọ́pọ̀ yanturu. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń gbádùn ayọ̀ tó wà nínú fífún àwọn èèyàn ní nǹkan bí wọ́n ti ń ‘ra àkókò padà’ kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan míì tí wọn ò bá máa fayé wọn ṣe. (Kól. 4:5; Ìṣe 20:35) Jèhófà ń rí ìsapá onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń ṣe, ó sì mọrírì ẹ̀ gidigidi. Kò sóhun tó lè kó àbùkù bá ìníyelórí ‘ìṣúra tí wọ́n ń kó pa mọ́ sí ọ̀run’ yìí. (Mát. 6:20; Héb. 6:10) Síwájú sí i, báwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe jẹ́ kí ‘ojú wọn mú ọ̀nà kan’ tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láti pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò, ńṣe ni àjọṣe wọn pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ ń dán mọ́rán sí i.—Mát. 6:22, 25, 32; Héb. 13:5, 6.
3. Kí nìyàtọ̀ tó wà láàárín lílépa ọrọ̀ nípa tẹ̀mí àti lílépa ọrọ̀ nípa tara?
3 Fífẹ́ láti di ọlọ́rọ̀ nípa tara sábà máa ń yọrí sí “ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́.” (1 Tím. 6:9, 10; Ják. 5:1-3) Èyí kò lè ṣẹlẹ̀ láé sí ìbùkún tí Jèhófà ń fúnni. Àkókò púpọ̀ táwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ni ò jẹ́ kí ipò dáadáa tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí yingin, ìyẹn ló sì ń jẹ́ kí wọ́n lè gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. (Fílí. 1:10) Arákùnrin kan tó jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ fi iṣẹ́ rẹ̀ tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀ kó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ tí ń tánni lókun gan-an ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí mò ń ṣe, àmọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Mo ti wá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ báyìí, mo sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó máa ń fúnni láyọ̀ ó sì ń gbádùn mọ́ni.”
4. Ọ̀nà wo làwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ń gbà rí ìbùkún báwọn náà ti ń bù kún àwọn ẹlòmíì?
4 Ìbùkún Fáwọn Ẹlòmíì: Lónìí gbogbo èèyàn ló ń kojú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Àwọn èèyàn níbi gbogbo ló ń wá ohun tó máa fún wọn nírètí lójú méjèèjì. Ayọ̀ àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa ń pọ̀ sí i nígbà tí àwọn tí kò nírètí bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì wá gbà gbọ́ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ẹ wo bí ayọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó ń fi ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún mẹ́jọ wákàtí [800] lọ́dọọdún lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí á ti pọ̀ tó!—1 Tím. 4:16.
5, 6. Kí lo lè ṣe tó o bá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé?
5 Ǹjẹ́ o ti ń ronú dáadáa lórí ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Ó lè béèrè pé kó o ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ kúrò nínú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan. (Éfé. 5:15, 16) Ọ̀pọ̀ ló ti ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọn ò sì ṣe jura wọn lọ, èyí ti wá mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dín àkókò tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù kí wọ́n bàa lè lo àkókò púpọ̀ sí i fún ire Ìjọba Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà á ṣètò ara ẹ kó o bàa lè dara pọ̀ mọ́ wọn?
6 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o bàa lè ṣètò tó gbéṣẹ́. (Ják. 1:5) Àwọn ìbùkún wo lèyí máa mú wá? Ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀ tẹ̀mí ló máa yọrí sí! Jèhófà á tún bù kún ẹ nípa tara. (Mát. 6:33) Gbogbo ẹni tó bá fọ̀rọ̀ yìí dán Jèhófà wò ló máa rí ‘ìbùkún gbà títí tí àìní kò fi ní sí mọ́.’—Mál. 3:10.