ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 30-31
  • Pinnu Láti Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìjọsìn Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pinnu Láti Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìjọsìn Ọlọ́run
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣó O Lè Ní Méjèèjì?
  • Yíyàn Tó Ò Ní Kábàámọ̀
  • Àǹfààní Tí Ò Lóǹkà
  • Ọrọ̀ Tó Ń Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • O Lè Di Ọlọ́rọ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 30-31

Pinnu Láti Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìjọsìn Ọlọ́run

KÍKÓ dúkìá jọ máa ń gba ìsapá gidigidi àti ìfara-ẹni-rúbọ. Bó sì ṣe rí náà nìyẹn béèyàn bá fẹ́ láti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Ìyẹn ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” (Mátíù 6:20) Fífọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run kì í ṣàdédé wáyé. Nítorí pé ọ̀tọ̀ ni kéèyàn lẹ́sìn, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn fọwọ́ pàtàkì mú un. Ó ṣe tán, pé èèyàn lówó sí báńkì ó fi dandan sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, dídi ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ àti títẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run gba ìpinnu, àkókò, ìsapá lójú méjèèjì àti ìfara-ẹni-rúbọ.—Òwe 2:1-6.

Ṣó O Lè Ní Méjèèjì?

Ṣé kò ṣeé ṣe kéèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run kéèyàn sì tún ní ọ̀pọ̀ dúkìá ni? Bóyá ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ọ̀kan nínú ẹ̀ ló dájú hán-ún hán-ún pé èèyàn lè lé bá. Jésù sọ pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24b) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò ṣeé ṣe láti máa wá béèyàn á ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run kéèyàn sì tún máa lépa àtikó dúkìá jọ. Ọ̀kan á ta ko èkejì ṣáá ni. Nítorí náà, kó tó di pé Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n to ìṣúra tẹ̀mí jọ, ó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 6:19.

Bá a bá rẹ́ni tí ò kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù tó wá ń gbìyànjú láti wá bóun ṣe máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tó sì tún ń lépa ọrọ̀, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sónítọ̀hún? Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì.” (Mátíù 6:24a) Kódà, béèyàn bá ní kóun máa lépa méjèèjì, kò sígbà tí ṣíṣe ojúṣe ẹni sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ò ní dà bí ohun ìdíwọ́ tí ò jẹ́ kéèyàn ráyè ṣe ohun tó fẹ́ ṣe. Bí wàhálà ìgbésí ayé bá wá dé, dípò kéèyàn gbára lé Ọlọ́run, èèyàn lè máa ronú pé bí owó àti ohun tí owó lè rà bá ṣáà ti wà, a jẹ́ pé àbùṣe bùṣe nìyẹn. Abájọ, bí Jésù ṣe sọ gan-an ló rí pé: “Ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.”—Mátíù 6:21.

Ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa gbé irú àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì bí èyí yẹ̀ wò gidigidi kó tó pinnu ohun táá máa lo àkókò ẹ̀ lé lórí, ohun táá máa fún láfiyèsí àti ohun táá máa fọkàn rò. Ti pé Ọlọ́run ò dá gbèdéke lé bí ohun tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ní á ṣe pọ̀ tó ò túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní jìyà ẹ̀ béèyàn ò bá tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tó fúnni nípa ìwọra. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) A ti wá rí i báyìí pé àwọn tí ò bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n sì pinnu pé àwọn á di ọlọ́rọ̀ kì í ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, bí wọ́n ṣe ń ro igbá ni wọ́n á máa ro àwo, ọkàn wọn kì í sì í balẹ̀. (Gálátíà 6:7) Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé ọ̀rọ̀ àwọn tó bá fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run ò ní rí bẹ́ẹ̀, ó sọ pé wọ́n á jẹ́ aláyọ̀. (Mátíù 5:3) Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá wa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ mọ ohun tó dára jù lọ tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè láyọ̀ ká sì lè wà ní àlàáfíà ara!—Aísáyà 48:17, 18.

Yíyàn Tó Ò Ní Kábàámọ̀

Èwo ni wàá yàn nínú méjèèjì, Ọlọ́run ni àbí ọrọ̀? Ó hàn gbangba pé a gbọ́dọ̀ fún àwọn nǹkan tá a ṣaláìní nípa tara ní àfiyèsí. Torí pé nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí Tímótì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn karí owó, àmọ́ kí wọ́n gbé e karí Ọlọ́run kí wọ́n “sì jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (1 Tímótì 5:8; 6:17, 18) Kí ni wàá fi ṣe àfojúsùn rẹ? Kí ni wàá máa lépa? Pàtàkì jù lọ lára àwọn iṣẹ́ àtàtà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa rẹ̀ ni wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́. (Mátíù 28:19, 20) Báwọn Kristẹni bá ń gbé ìgbé ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí kì í wulẹ̀ ṣe pé wọ́n dín ohun tí wọ́n ń ṣe kù kí wọ́n ṣì lè máa dọ́gbọ́n jayé, àmọ́ tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ tó nítumọ̀ yìí, a jẹ́ pé wọ́n ń “to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la” nínú ayé tuntun Ọlọ́run nìyẹn. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ṣáá o, àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run “sàn ju wúrà” lọ!—1 Tímótì 6:19; Òwe 16:16; Fílípì 1:10.

Gbé ìrírí ti Eddie, tí ìdílé rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó wà lọ́mọdé yẹ̀ wò. Ọ̀ràn náà burú débi pé ìdílé rẹ̀ pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní, ó sì di dandan kí wọ́n kó kúrò nínú ilé tí wọ́n ń gbé. Eddie ṣàlàyé pé: “Ìgbà gbogbo ni mo ti máa ń ṣàníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá di pé kò sí nǹkan kan lọ́wọ́ wa mọ́. Kò sì wá sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wa mọ́ báyìí. Ṣẹ́ ẹ wá mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Kò sí láburú kankan! A ṣì ń jẹ, á ṣì ń mu, a ṣì ń rí aṣọ wọ̀ sọ́rùn. Jèhófà ò jẹ́ kóun tá a nílò wọ́n wa, kò sì pẹ́ tọ́wọ́ wa fi padà tẹ àwọn ohun tá a ṣaláìní. Ibi tọ́rọ̀ wa wá padà já sí yìí jẹ́ kí n rí ìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ máa fọwọ́ pàtàkì mú ìlérí tí Jésù ṣe nínú Mátíù 6:33 pé bá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run ṣe ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, kò tún yẹ ká máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a ṣaláìní nípa tara mọ́.” Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, Eddie àti ìyàwó ẹ̀ ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, alákòókò kíkún. Wọ́n rí ná wọ́n rí lò. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.

Àǹfààní Tí Ò Lóǹkà

Níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ò dà bíi dúkìá táwọn olè lè jí, ńṣe ló máa ń wà títí lọ. (Òwe 23:4, 5; Mátíù 6:20) Òótọ́ ni pé ó máa ń ṣòro láti díwọ̀n gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Àti pé kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti pinnu ibi tí ìfẹ́, ayọ̀, tàbí ìgbàgbọ́ ẹnì kan pọ̀ dé bó ṣe máa ń rọrùn láti mọ bí owó téèyàn ní ṣe pọ̀ tó. Àmọ́ èrè tó wà nínú kéèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ò lóǹkà. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n á fi ilé àti pápá, ìyẹn ọ̀nà àtijẹ àtimu wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè ráyè bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn, ó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni, àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.

Kí ni wàá fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé Ọlọ́run ni àbí ọrọ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

Ṣé ọrọ̀ lo gbájú mọ́ . . .

. . . àbí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́