ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/02 ojú ìwé 8
  • Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn sí “Àwọn Ọmọdékùnrin Aláìníbaba”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn sí “Àwọn Ọmọdékùnrin Aláìníbaba”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bàbá Àwọn Ọmọ Aláìníbaba
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan Lè Kẹ́sẹ Járí!
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Máa Fi Ìgbatẹnirò Hàn fún Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 11/02 ojú ìwé 8

Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn sí “Àwọn Ọmọdékùnrin Aláìníbaba”

1 Jèhófà ni “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Sm. 68:5) Láti fi hàn pé Jèhófà kò fọ̀rọ̀ wọn ṣeré rárá, ó pa àṣẹ kan fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, èyí tó sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́. Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà.” (Ẹ́kís. 22:22, 23) Òfin Ọlọ́run tún ní ètò fún ríran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti rí àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara. (Diu. 24:19-21) Lábẹ́ ìṣètò ti Kristẹni, a gba àwọn olùjọsìn níyànjú “láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.” (Ják. 1:27) Báwo la ṣe lè fara wé ìfẹ́ àtọkànwá tí Jèhófà ní sí àwọn ọmọ tí wọ́n ń tọ́ nínú ìdílé olóbìí kan tàbí nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

2 Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Tẹ̀mí: Bó o bá jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ tàbí kẹ̀ tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ jẹ́ aláìgbàgbọ́, dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ lè má rọrùn. Àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tó bá ohun tí ìdílé yín nílò mu ṣe pàtàkì bí àwọn ọmọ rẹ yóò bá di àgbàlagbà tó wà déédéé tó sì dàgbà dénú. (Òwe 22:6) Bíbá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí lójoojúmọ́ tún ṣe pàtàkì. (Diu. 6:6-9) Nígbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá ọ, àmọ́ má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Máa tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà pé kó fún ọ lókun àti ìtọ́sọ́nà bó o ti ń “bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ rẹ] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfé. 6:4.

3 Bó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ yàn fún ọ, jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ ibi tí bàtà ti ń ta ọ́ lẹ́sẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fún ọ ní àwọn ìdámọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tàbí kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fìdí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó jíire múlẹ̀ nínú ìdílé rẹ.

4 Bí Àwọn Mìíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́: Ní ọ̀rúndún kìíní, Tímótì di ìránṣẹ́ onítara fún Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti dàgbà. Kò sí àní-àní pé ìsapá aláápọn tí ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ ṣe láti kọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́ nígbà tó wà léwe kó ipa pàtàkì nínú bó ṣe di onítara. (Ìṣe 16:1, 2; 2 Tím. 1:5; 3:15) Àmọ́ ṣá o, ó tún jàǹfààní látinú bíbá àwọn Kristẹni mìíràn kẹ́gbẹ́, irú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tó tọ́ka sí Tímótì gẹ́gẹ́ bí “ọmọ [òun] olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa.”—1 Kọ́r. 4:17.

5 Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí o, ẹ ò rí i pé ó máa ń ṣàǹfààní gan-an ni nígbà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí bá fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin aláìníbaba tó wà nínú ìjọ! Ṣé o mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn? Ṣé o máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni àti láwọn ìgbà mìíràn? Ké sí wọn pé kẹ́ ẹ jọ lọ sí òde ẹ̀rí. Bóyá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ní kí àwọn ọmọ náà àti òbí tó ń dá tọ́ wọn tàbí òbí tó jẹ́ onígbàgbọ́, dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín tàbí nínú àwọn ètò tẹ́ ẹ ṣe fún eré ìtura tó gbámúṣé. Nígbà táwọn èwe wọ̀nyí bá rí i pé ọ̀rẹ́ àwọn lo jẹ́, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún wọn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ wọ́n á sì gba ìṣírí tó ò ń fún wọn.—Fílí. 2:4.

6 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìníbaba gan-an ni, ó sì ń bù kún ìsapá onífẹ̀ẹ́ wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó dàgbà nínú ìdílé olóbìí kan tàbí nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti rí irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ gbà, wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, alàgbà, alábòójútó arìnrìn-àjò, míṣọ́nnárì tàbí bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pátá máa wá àwọn ọ̀nà tá a lè fi “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ wa fún àwọn tó jẹ́ aláìníbaba, ní àfarawé Baba wa ọ̀run.—2 Kọ́r. 6:11-13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́