Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí Bibeli ti sábà máa ń mẹ́nukan “ọmọdékùnrin aláìníbaba,” èyí ha fi ìdàníyàn tí ó dínkù fún àwọn ọmọdébìnrin hàn bí?
Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́.
Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures lo àpólà-ọ̀rọ̀ náà “ọmọdékùnrin aláìníbaba” nínú ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ tí ó fi ìdàníyàn Ọlọrun hàn fún àwọn ọmọdé tí wọ́n ṣaláìní òbí kan. Ọlọrun mú ìdàníyàn yìí ṣe kedere nínú àwọn òfin tí ó fifún Israeli.
Fún àpẹẹrẹ, Ọlọrun sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ pọ́n opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba lójú. Bí ìwọ bá jẹ́ pọ́n ọn lójú rárá, bí òun nígbà náà bá sì ké pè mí, èmi kì yóò kùnà láti gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀; ìbínú mi yóò sì ru lójijì nítòótọ́, èmi yóò sì fi idà pa ọ́ dájúdájú, àwọn aya rẹ sì gbọ́dọ̀ di opó àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò sì di ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Eksodu 22:22-24, NW) “OLUWA Ọlọrun yín, Ọlọrun àwọn ọlọrun ni àti Oluwa àwọn oluwa, Ọlọrun títóbi, alágbára, àti ẹlẹ́rù, tí kìí ṣe ojúṣàájú, bẹ́ẹ̀ ni kìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Òun níí máa ṣe ìdájọ́ [ọmọdékùnrin, NW] aláìníbaba àti opó.”—Deuteronomi 10:17, 18; 14:29; 24:17; 27:19.
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dà-ìtúmọ̀ Bibeli kà pé “ọmọ aláìníbaba” tàbí “ọmọ aláìlóbìí” nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, nípa báyìí ó kó àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, irú àwọn ìtúmọ̀ bẹ́ẹ̀ gbójúfo ẹwà-ọ̀rọ̀ kan tí ó wà lábẹ́nú ọ̀rọ̀ Heberu náà (ya·thohmʹ), tí ó jẹ́ jẹ́ńdà akọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, New World Translation of the Holy Scriptures lo ìtúmọ̀ tí ó péyé náà “(àwọn) ọmọdékùnrin aláìníbaba,” gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní Orin Dafidi 68:5, (NW) tí ó kà pé: “Baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọrun nínú ibùgbé mímọ́ rẹ̀.” Nítorí ẹ̀mí-ìmọ̀lára abẹ́nú kan-náà tí a ní fún ọ̀rọ̀ Heberu náà, jẹ́ńdà abo ti ọ̀rọ̀-ìṣe kan nínú Orin Dafidi 68:11 (NW) dámọ̀ràn kíkà náà pé: “Àwọn obìnrin tí ń sọ̀rọ̀ ìhìnrere jẹ́ ẹgbẹ́-ọmọ-ogun ńlá.”a
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọmọdékùnrin aláìníbaba” ni ìtúmọ̀ pàtàkì fún ya·thohmʹ, èyí ni a kò níláti gbà bí ọ̀kan tí ń dábàá àìsí ìdàníyàn fún àwọn ọmọdébìnrin tí kò ní òbí. Àwọn apá-àyọkà-ọ̀rọ̀ náà tí a fàyọ àti àwọn mìíràn fihàn pé àwọn ènìyàn Ọlọrun ni a fún ní ìṣírí láti tọ́jú àwọn obìnrin, àwọn opó. (Orin Dafidi 146:9; Isaiah 1:17; Jeremiah 22:3; Sekariah 7:9, 10; Malaki 3:5) Nínú Òfin, Ọlọrun tún fi àkọsílẹ̀ kan kún un nípa ìpinnu ìdájọ́ tí ó pèsè ìdánilójú nípa ogún fún àwọn aláìníbaba ọmọbìnrin Selofehadi. Àṣẹ ìdájọ́ yẹn di ìlànà òfin fún bíbójútó irú àwọn ipò-ọ̀ràn kan-náà, tí ó tipa báyìí ń gbé ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdébìnrin aláìníbaba lárugẹ.—Numeri 27:1-8.
Jesu kò fìyàtọ̀ sí ẹ̀yà ti akọ tàbí ti abo níti fífi inúrere hàn sí àwọn ọmọdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, a kà pé: “Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá, kí ó lè fi ọwọ́ tọ́ wọn: àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí i, inú bí i, ó sì wí fún wọn pé, Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré kí ó wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọ kékeré, kì yóò lè wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí. Ó sì gbé wọn sí apá rẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, ó sì súre fún wọn.”—Marku 10:13-16.
Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “àwọn ọmọ kékeré” níhìn-ín wà ní jẹ́ńdà kò-ṣe-akọ-kò-ṣe-abo. Ìwé atúmọ̀-èdè Griki kan tí a mọ̀ bí-ẹni-mowó sọ pé ọ̀rọ̀ yìí “ni a ń lò fún àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin.” Jesu ń fi ọkàn-ìfẹ́ kan-náà bíi ti Jehofa hàn fún gbogbo àwọn ọmọdé, lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin. (Heberu 1:3; fiwé Deuteronomi 16:14; Marku 5:35, 38-42.) Nípa báyìí a níláti mọ̀ pé ìmọ̀ràn inú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu lórí bíbójútó “àwọn ọmọkùnrin aláìníbaba” jásí àmọ̀ràn lórí bí a ṣe níláti ní ìdàníyàn nípa gbogbo àwọn ọmọdé tí kò ní òbí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tanakh ti àwọn Ju kà pé: “OLUWA pàṣẹ kan pé; àwọn obìnrin tí ń mú ìhìn wá jẹ́ ẹgbẹ́-àwọn-ọmọ-ogun ńlá.”