ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 2/8 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Àmì Ìgbàlódé Ni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Àmì Ìgbàlódé Ni
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Fífòpin Sí Ìṣòro Náà
    Jí!—2000
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • Àwọn Bàbá—Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń di Àwátì
    Jí!—2000
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 2/8 ojú ìwé 3

Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Àmì Ìgbàlódé Ni

KÍ LO rò pé ó jẹ́ ìṣòro tó burú jù láwùjọ ẹ̀dá lóde òní? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgọ́rin lára àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò tó sọ pé, “àìsí bàbá nínú ìdílé ni.” Ìwádìí náà fi hàn pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ọmọdé tí ò gbé pẹ̀lú bàbá wọn, ńṣe ni wọ́n sì ń yára pọ̀ sí i. Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Fún Àwọn Ọmọdé gbé ìròyìn kan jáde tó sọ pé nǹkan bí ìpín àádọ́ta lára àwọn ọmọ òyìnbó tí wọ́n ń bí ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti ọdún 1980 “ló máa lò lára ìgbà ọmọdé wọn nínú ìdílé olóbìí kan. Ní ti àwọn ọmọ adúláwọ̀, iye wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún.” Ìdí nìyẹn tí ìwé ìròyìn USA Today fi sọ pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà “ló gba iwájú lágbàáyé nínú ọ̀ràn wíwà tí ìdílé ń wà láìsí bàbá.”

Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Atlantic Monthly sọ pé: “Kì í ṣe àárín àwọn ọmọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan ni ọ̀ràn títú tí ìdílé ń tú ká ti ń ṣẹlẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ló ti ń ṣẹlẹ̀, títí kan Japan pàápàá.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ bí iye wọ́n ṣe pọ̀ tó ní ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ó jọ pé àwọn náà ń ní irú ìṣòro kan náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn World Watch ṣe sọ, “àwọn ọkùnrin [ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà] sábà máa ń já àwọn ìyàwó àti ọmọ wọn sílẹ̀ nítorí àìrówó gbọ́ bùkátà wọn.” Ìwádìí kan tí wọ́n tiẹ̀ ṣe ní orílẹ̀-èdè kan ní àgbègbè Caribbean fi hàn pé ìpín méjìlélógún péré nínú àwọn bàbá tí wọ́n ní àwọn ọmọ tó ti pé ọdún mẹ́jọ ló ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.

Ká sòótọ́, àwọn ọmọ aláìníbaba wà nígbà tí a kọ Bíbélì pàápàá. (Diutarónómì 27:19; Sáàmù 94:6) Àmọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ikú ni lájorí ohun tó ń sọ àwọn ọmọ di aláìníbaba. Àmọ́, òǹkọ̀wé David Blankenhorn sọ pé: “Kí bàbá ṣàdédé jáde nílé, kó sì já wọn sílẹ̀ ló ń fa tòde òní.” A ṣì máa rí i nínú ìwé yìí pé kò sí àní-àní pé pípọ̀ tí iye àwọn ọmọ aláìníbaba ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ló jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” Bí Bíbélì sì ti sọ, ẹ̀rí míì lèyí jẹ́ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí.—2 Tímótì 3:1-3.

Ṣùgbọ́n ìbìnújẹ́ gbáà ló máa ń jẹ́ fún àwọn ọmọdé bí bàbá wọn bá di àwátì. Ó máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ ojoojúmọ́, tí àtúbọ̀tán rẹ̀ kì í lọ lára wọn bọ̀rọ̀. Nítorí náà, ohun táa fẹ́ jíròrò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn, ṣùgbọ́n kì í sì í ṣe torí àtiba ẹ̀yin tí ẹ ń kàwé wa lọ́kàn jẹ́ la ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe torí àtiṣàlàyé tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro yìí tó ń ba ìdílé jẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́