Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí làwọn àǹfààní tó wà nínú dídara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń ṣe ìpínlẹ̀ tí à ń gbé?
Nípasẹ̀ ìṣètò ìjọ la fi ń rí ìṣírí gbà, èyí tó ń ‘ru wá sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’ (Héb. 10:24, 25) Nípasẹ̀ ìjọ la fi ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tá a sì ń di ẹni tá a mú gbára dì láti ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá a yàn fún wa. (Mát. 28:19, 20) A tún ń rí okun gbà láti fara da àwọn àdánwò pẹ̀lú ìṣòtítọ́, a sì tún ní àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn wàhálà àti àníyàn tó túbọ̀ ń peléke sí i. Láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n, ìjọ ṣe pàtàkì fún wa láti lè dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Bó ti wù kó rí, ǹjẹ́ àǹfààní tiẹ̀ wà nínú dídara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń ṣe ìpínlẹ̀ tí à ń gbé?
Ipò kálukú wa yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì làwọn nǹkan bí irú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tẹ́nì kan ń ṣe, níní ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, àti wíwọkọ̀-lọ-wọkọ̀-bọ̀, lè nípa lórí irú ìpinnu tí ẹnì kan máa ṣe lórí ọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, àwọn àǹfààní gidi wà níbẹ̀, nípa tara àti nípa tẹ̀mí, tí ẹnì kan bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń ṣe ìpínlẹ̀ ibi tó ń gbé. Á ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà láti tètè kan gbogbo àwọn akéde lára tí àwọn ìṣòro pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Àwọn Àpótí Ìbéèrè tó ti kọjá ti sọ díẹ̀ lára àwọn àǹfààní mìíràn tí èyí ní nínú.—June 1991, August 1976, àti January 1968.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń rọrùn jù láti lọ sí ìpàdé tó wà nítòsí, èyí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti tètè dé ìpàdé ká lè bá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀, ká lè mójú tó àwọn ohun pàtàkì tó yẹ ní ṣíṣe, ká sì lè kópa nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀. Bí àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn bá ń gbé ládùúgbò wa, ó túbọ̀ máa ń ṣeé ṣe fún wa láti dé ọ̀dọ̀ wọn, ká ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn, ká sì darí wọn sí àwọn ìpàdé tó máa rọrùn fún wọn jù lọ láti máa lọ.
Ó dá wa lójú pé àwọn olórí ìdílé yóò fi tàdúràtàdúrà gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, àti pé wọ́n á fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò gbogbo kókó tó so mọ́ pípinnu ohun tó máa ṣe ìdílé wọn láǹfààní jù lọ nípa tẹ̀mí àti nípa tara.—1 Tím. 5:8.