Gbígbé Níbàámu Pẹ̀lú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Wa
1 Yálà o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni tàbí o ti ṣe é ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, kò sí àní-àní pé o máa ń rántí ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìrìbọmi wa kì í ṣe òpin, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé kan tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà láti fi ṣiṣẹ́ sìn ín, èyí tó lè máa bá a lọ títí láé. (1 Jòh. 2:17) Kí ni gbígbé níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ní nínú?
2 Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Kristi: Gbàrà tí Jésù ṣèrìbọmi tán, “ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀,” ìyẹn pípolongo “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:23; 4:43) Bákan náà, àtìgbà tí àwa náà ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi la ti di òjíṣẹ́ ìhìn rere náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè pọn dandan pé ká lo ọ̀pọ̀ àkókò, ká sì sapá gidigidi láti lè ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni olórí iṣẹ́ wa. (Mát. 6:33) Dípò kí àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run máa ṣe kìràkìtà láti kó ọrọ̀ jọ tàbí láti máa wá ipò iyì, wọ́n máa ń wá bí wọ́n á ṣe ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lógo’ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe. (Róòmù 11:13) Ǹjẹ́ o mọrírì àǹfààní ńlá tó o ní láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, ṣé o sì ń lo àǹfààní náà lọ́nà tó dára jù lọ?
3 A gbọ́dọ̀ “kọ ojú ìjà sí Èṣù” gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Ják. 4:7) Lẹ́yìn ìbatisí Jésù, Sátánì dán an wò, bákan náà ló sì ṣe dájú sọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un. (Lúùkù 4:1-13) Níwọ̀n bí ayé Sátánì ti yí wa ká, a gbọ́dọ̀ máa sẹ́ ara wa, ká máa yàgò fún ohunkóhun tó lè sọ ìrònú wa dìdàkudà tàbí tó lè sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin. (Òwe 4:23; Mát. 5:29, 30) A fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé wọn “kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́r. 10:21) Èyí ń béèrè pé ká ṣọ́ra fún àwọn eré ìnàjú tí kò bójú mu, ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, àtàwọn ewu tó so mọ́ lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó tún ń béèrè pé ká yàgò fún àwọn ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn apẹ̀yìndà. Wíwà lójúfò sí àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn ọgbọ́n àrékérekè mìíràn tí Sátánì ń lò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa.
4 Máa Lo Àwọn Ìpèsè Ọlọ́run: Láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa, Jèhófà ti pèsè ìrànlọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. Jẹ́ kí Bíbélì kíkà àti gbígbàdúrà sí Jèhófà wà lára àwọn ohun tí wàá máa ṣe lójoojúmọ́. (Jóṣ. 1:8; 1 Tẹs. 5:17) Máa nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí àwọn ìpàdé ìjọ. (Sm. 122:1) Máa bá àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ kẹ́gbẹ́ pọ̀.—Sm. 119:63.
5 Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, o lè gbé níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ sí Jèhófà, tí wàá sì máa rí ìdùnnú nínú sísìn ín títí láé.—Sm. 22:26, 27; Fílí. 4:13.