Iṣẹ́ Kan Tó Ń Béèrè Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé kí a jẹ́ “onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, kí [a] má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe . . . ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí [a] máa súre.” (1 Pét. 3:8, 9) Dájúdájú, ìmọ̀ràn yẹn wúlò nínú iṣẹ́ ìwàásù. Láìsí àní-àní, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni lè dán ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa wò.
2 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ànímọ́ kan tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ipò tí kò bára dé. Nígbà tá a bá ń wàásù, a máa ń lọ bá àwọn èèyàn tí a kò mọ̀ rí láìjẹ́ pé wọ́n ké sí wa, a sì mọ̀ pé àwọn kan kò ní hùwà ọmọlúwàbí sí wa. Láti lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ lójú irú ipò bẹ́ẹ̀, a nílò ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ní ìpínlẹ̀ kan tí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣòro gan-an, àwọn arábìnrin aṣáájú ọ̀nà méjì máa ń lọ wàásù láti ilé dé ilé lójoojúmọ́ fún odindi ọdún méjì láìrí ẹnì kan ṣoṣo tó dá wọn lóhùn lẹ́nu ọ̀nà! Àmọ́ wọn ò jáwọ́ o, lónìí, ìjọ méjì ló wà ní àgbègbè náà.
3 Ohun Tá A Lè Ṣe Bí Wọn Bá Fàbùkù Kàn Wá: Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara wé Jésù nígbà tí àwọn ẹlòmíràn kò bá fi inú rere bá wa lò tàbí tí wọ́n bá hùwà àìlọ́wọ̀ sí wa. (1 Pét. 2:21-23) Ní ilé kan tí arábìnrin kan dé, ìyàwó onílé náà ló kọ́kọ́ bú u, lẹ́yìn náà ni ọkọ obìnrin náà tún bú u, tó sì sọ fún un pé kó jáde nílé àwọn. Ńṣe ni arábìnrin náà kàn rẹ́rìn-ín músẹ́, tó sì sọ pé òun nírètí láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà mìíràn. Èyí wú tọkọtaya náà lórí débi pé, wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí mìíràn tó wá sílé wọn lẹ́yìn náà, wọ́n sì gbà láti wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Arábìnrin tí wọ́n kàn lábùkù náà wà níbẹ̀, ó kí wọn káàbọ̀ ó sì tún jẹ́rìí fún wọn. Àwa náà lè mú kí ọkàn àwọn tí kì í fẹ́ tẹ́tí sí wa rọ̀ nípa fífi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” hàn sí wọn.—1 Pét. 3:15; Òwe 25:15.
4 Má Ṣe Jọ Ara Rẹ Lójú: Ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ látinú Bíbélì kò fàyè gbà wá láti máa wo àwọn èèyàn bíi pé wọn kò já mọ́ nǹkan kan tàbí ká máa lo èdè àbùkù fún wọn. (Jòh. 7:49) Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́.” (Títù 3:2) Bí a bá jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà bíi ti Jésù, a óò mú kí ara tu àwọn ẹlòmíràn. (Mát. 11:28, 29 ) Bíbá àwọn èèyàn lò pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ túbọ̀ ń buyì kún ìhìn tí à ń jẹ́.
5 Ní tòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa wàásù nìṣó ní ìpínlẹ̀ tó ṣòro. Ó lè mú kí ọkàn àwọn tí kì í fẹ́ tẹ́tí sílẹ̀ rọ̀, ó sì máa ń mú kí àwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Ìjọba náà. Lékè gbogbo rẹ̀, ó ń mú inú Jèhófà dùn, ẹni tó ń “fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pét. 5:5.