ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 1/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 13

Orin 69

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! February 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! February 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

15 min: Jíròrò “Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú.”

15 min: “Gbígbé Níbàámu Pẹ̀lú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Wa.”a Lẹ́yìn jíjíròrò ìpínrọ̀ 3, ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀dọ́ kan tó ti dàgbà díẹ̀ tàbí ọ̀dọ́langba kan tó ti ṣèrìbọmi lẹ́nu wò. Àwọn ìpèníjà wo ló ti dojú kọ látìgbà tó ti ṣèrìbọmi? Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpèníjà náà? Ọ̀nà wo ló ti gbà jàǹfààní látinú bó ṣe ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà?

Orin 22 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 20

Orin 44

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Rọ gbogbo àwọn ará láti máa lo ìwé pẹlẹbẹ Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2003. Jíròrò àlàyé tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú, ní ojú ìwé 3 àti 4. Sọ ohun tí àwọn ìdílé lè ṣe láti máa jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pa pọ̀. Láti fi àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ hàn, jíròrò àpẹẹrẹ méjì tàbí mẹ́ta látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àlàyé tí a óò gbé yẹ̀ wò ní oṣù tó ń bọ̀. Ṣe àṣefihàn kúkúrú kan nípa tọkọtaya kan tí wọ́n jọ ń ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní àti àlàyé rẹ̀.

22 min: “Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Ní Èdè Mímọ́ Gaara.”b Lẹ́yìn jíjíròrò ìpínrọ̀ 6, jẹ́ kí akéde kan tó dáńgájíá ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà onílé nígbà tá a bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò, nípa lílo ọ̀kan lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002, ní ojú ìwé 4. Kí akéde náà gbé ìpínrọ̀ kan yẹ̀ wò nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Jẹ́ kí akéde náà kádìí rẹ̀ nípa bíbéèrè ìbéèrè kan látinú ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e, kó sì ṣètò láti wá dáhùn rẹ̀ nígbà tó bá tún padà wá. Rọ gbogbo àwọn ará láti ṣàyẹ̀wò bóyá èyíkéyìí lára àwọn tí wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn á nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yìí.

Orin 68 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 27

Orin 92

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! February 8 lọni. Lo àbá kejì tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! February 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kí akéde kádìí rẹ̀ nípa fífún àwọn onílé ní ìwé ìléwọ́ náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?—kí wọ́n fún ẹni tó gba àwọn ìwé ìròyìn náà àti ẹni tí kò gbà á. Ṣe àlàyé ṣókí nípa bí a ṣe lè padà bẹ àwọn tó gba ìwé ìròyìn wò nígbà tá a bá fún wọn ní ìwé ìléwọ́ náà.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 2002, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 10.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: Lo Ìwé Ìmọ̀ Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní oṣù February, a fẹ́ sapá láti bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Fọ̀rọ̀ wá akéde kan lẹ́nu wò, ẹni tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan láìpẹ́ yìí nínú ìwé Ìmọ̀, kí ó ṣàlàyé bó ṣe ṣe é. Rán olúkúlùkù létí nípa “Àwọn Àbá fún Fífi Ìwé Ìmọ̀ Lọni” tó wà ní ojú ìwé 5 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002, kí o sì ṣàṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn àbá náà.

Orin 148 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 3

Orin 9

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò Àpótí Ìbéèrè. Rọ àwọn akéde láti lo fọ́ọ̀mù tó ń jẹ́ Please Follow Up (S-43) nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè mìíràn. Ohun tó yẹ ká máa lo fọ́ọ̀mù yìí fún nìyí kódà bí ẹni náà kò bá fi ìfẹ́ hàn sí ìhìn Ìjọba náà.

12 min: Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn. Fọ̀rọ̀ wá alàgbà kan lẹ́nu wò, tó ti ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. (Héb. 13:7) Báwo ló ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Àwọn ìdènà wo ló ní láti ṣẹ́pá rẹ̀ kó lè dúró ṣinṣin nínú òtítọ́? Àwọn ìpèsè tẹ̀mí tàbí àwọn ìṣírí tẹ̀mí wo ló ràn án lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú? Kí làwọn ohun tó ṣe láti nàgà fún dídi alábòójútó nínú ìjọ? (1 Tím. 3:1) Kí ló ti ràn án lọ́wọ́ láti máa bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ, lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti nínú ìdílé, tí ọ̀kan kò sì pa òmíràn lára? (1 Tím. 5:8) Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ pé ó ní àǹfààní láti máa ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ nínú ìjọ?

18 min: “Iṣẹ́ Kan Tó Ń Béèrè Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ké sí àwùjọ láti sọ ohun tá a lè ṣe bí ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ wa bá fẹ́ fi wá ṣẹ̀sín tàbí tó hùwà àìlọ́wọ̀ sí wa, tó jẹ́ alásọ̀ tàbí oníbìínú èèyàn. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé kún un látinú ìwé Insight, Apá Kìíní, ojú ìwé 1160, ìpínrọ̀ 3.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́