Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Ní Èdè Mímọ́ Gaara
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látinú ọ̀pọ̀ ‘orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ènìyàn, àti ahọ́n’ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá, wọ́n wà níṣọ̀kan, wọ́n jẹ́ ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé. (Ìṣí. 7:9) Nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tá à ń gbé yìí, èyí jọni lójú gan-an ni. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Nítorí pé a ti fún wa ní “ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara” ni.—Sef. 3:9.
2 Àwọn Àbájáde Kíkàmàmà: Kí ni èdè mímọ́ gaara yìí? Ó jẹ́ níní òye kíkún nípa òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀, ní pàtàkì jù lọ, òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, à ń lo ọ̀nà kan lórí ilẹ̀ ayé lónìí láti pín òtítọ́ yìí kiri, ìyẹn ni nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” àbájáde èyí sì ni pé, àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́.—Mát. 24:45; Sek. 8:23.
3 Bí àwọn èèyàn ti ń kọ́ èdè mímọ́ gaara náà, ó ń sún wọn láti mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Jèhófà mu. Wọ́n ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè di ẹni tí a “so . . . pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́r. 1:10) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tún ń jẹ́ kí wọ́n lè máa hu ìwà rere kí wọ́n sì máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó bójú mu, tó jẹ́ òtítọ́, pàápàá jù lọ òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú sísọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Títù 2:7, 8; Héb. 13:15) Àwọn ìyípadà pípabanbarì yìí ń mú ọlá bá Jèhófà.
4 Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó gbọ́ ìhìn rere náà lẹ́nu akéde kan ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti béèrè, gbogbo rẹ̀ ló sì rí ìdáhùn sí látinú Bíbélì. Nítorí pé àwọn ohun tó gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ó sì tún ń wá sí ìpàdé. Bí wọ́n ṣe kí i káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yà á lẹ́nu, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oríṣiríṣi ẹ̀yà làwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Láàárín àkókò díẹ̀, òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Látìgbà náà, ó ti ran àwọn mìíràn tó ń lọ sí bí ogójì lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláàbọ̀ ara ni, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.
5 Kíkọ́ Àwọn Ẹlòmíràn: Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ti ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn máa tún ìrònú wọn àti ìgbésí ayé wọn gbé yẹ wò. Gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù, ó yẹ ká sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó gbéṣẹ́ ni yóò mú kí a lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti kọ́ èdè mímọ́ gaara yìí.
6 Ọ̀nà kan tó ti gbéṣẹ́ gan-an fún àwọn èèyàn tí ọwọ́ wọn máa ń dí ni ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò gba àkókò pẹ̀lú wọn lẹ́nu ọ̀nà wọn gan-an. (km-YR 5/02 ojú ìwé 1) Ǹjẹ́ o ti gbìyànjú èyí? Nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀ láti lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò kan, yan ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tó bá ipò onílé náà mu nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkìbọnú yìí la ṣe lọ́nà tó máa darí ìjíròrò náà ní tààràtà lọ sínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí sínú ìwé Ìmọ̀. Fí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà dánra wò dáadáa kó bàa lè rọrùn fún ọ láti lọ sínú jíjíròrò ọ̀kan lára àwọn ìpínrọ̀ náà lẹ́yìn tó o ti sọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀. Yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì nínú ìpínrọ̀ náà tí wàá kà tí wàá sì jíròrò, kí o sì múra ìbéèrè kan sílẹ̀ tí wàá béèrè ní ìparí ìjíròrò náà. Ìyẹn á jẹ́ àtẹ̀gùn sí ìpínrọ̀ tó o wéwèé láti jíròrò nígbà mìíràn tó o bá tún wá.
7 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún làwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn nítorí pé wọ́n ti kọ́ èdè mímọ́ gaara náà. Ẹ jẹ́ ká fi taápọntaápọn ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú ‘pípe orúkọ Jèhófà,’ àti ‘sísìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.’—Sef. 3:9.