ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 7
  • Fídíò Tó Máa Là Ọ́ Lóye Tí Yóò sì fún Ọ Níṣìírí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fídíò Tó Máa Là Ọ́ Lóye Tí Yóò sì fún Ọ Níṣìírí!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ
    Jí!—2001
  • Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn
    Jí!—2001
  • Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú Lọ sí Siberia!
    Jí!—1999
  • Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 7

Fídíò Tó Máa Là Ọ́ Lóye Tí Yóò sì fún Ọ Níṣìírí!

Oṣù April ọdún 1951 ni. Wọ́n ṣa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́, títí kan àwọn ìdílé lódindi, wọ́n kó wọn sínú ọkọ̀ ojú irin, wọ́n sì kó wọn nígbèkùn lọ sí Siberia. Kí ló dé tí ìjọba alágbára ilẹ̀ Soviet fi pinnu láti rẹ́yìn wọn? Báwo ni àwọn arákùnrin wa ṣe rù ú là, àní tí iye wọn tún pọ̀ sí i bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n fi ṣe inúnibíni sí wọn láìdáwọ́dúró? Wàá rí ìdáhùn nínú fídíò náà, Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union. Wò ó, kó o sì jẹ́ kí àwọn ìsọfúnni inú rẹ̀ tó kún fún ẹ̀kọ́ sún ọ láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí!

Ǹjẹ́ o lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí? (1) Ìgbà wo ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin ní orílẹ̀-èdè náà? (2) Ṣáájú àti lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ pé ilẹ̀ Soviet Union wá ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé Ẹlẹ́rìí sí i? (3) Báwo ni àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣe takora pẹ̀lú èròǹgbà Ààrẹ Lenin? (4) Kí ni wọ́n ń pè ní Operation North nígbà náà, kí sì ni Stalin retí láti lo ìlànà náà fún? (5) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí bí wọ́n bá lọ sígbèkùn, kí ni wọ́n sì sọ pé kí wọ́n ṣe bí wọn ò bá fẹ́ kí ìjọba kó wọn lọ? (6) Nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò gígùn náà nínú ọkọ̀ ojú irin lọ sí Siberia, báwo ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe fún ara wọn níṣìírí tí wọ́n sì mú kí ẹnu máa ya àwọn tó ń kó wọn lọ sígbèkùn? (7) Àwọn ìnira wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí fara dà ní Siberia? (8) Ìpèsè tẹ̀mí wo ni àwọn èèyàn Jèhófà mọrírì rẹ̀ gidigidi, fún ìdí wo sì ni? (9) Ìdí wo ni àwọn arákùnrin wa fi múra tán láti fi ẹ̀mí wọn wewu nítorí àtilè máa rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn gbà, báwo ni wọ́n sì ṣe borí láìka gbogbo ìsapá àwọn aláṣẹ láti dí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa rí i gbà? (10) Báwo ni Khrushchev ṣe ń bá ṣíṣe àtakò sáwọn èèyàn Ọlọ́run nìṣó? (11) Ọ̀nà wo ni àwọn aláṣẹ gbà gbìyànjú láti bomi paná ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí? (12) Òye tó ṣe kedere wo ni àwọn arákùnrin wa ní nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí wọn? (Ìwé 2002 Yearbook, ojú ìwé 203 àti 204) (13) Báwo ló ṣe jẹ́ pé òdìkejì ohun tí àwọn tó ń ṣàtakò gbígbóná janjan sí ètò àjọ Ọlọ́run retí ló ṣẹlẹ̀? (Ìwé 2002 Yearbook, ojú ìwé 220 àti 221) (14) Àwọn nǹkan wo ló wá tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ lọ́wọ́, èyí tó ti dà bí àlá nígbà kan rí? (15) Kí lohun náà tó mú kí àwọn arákùnrin wa lè fara da àwọn àdánwò wọn, báwo sì ni apá tó kẹ́yìn nínú fídíò náà ṣe fi hàn pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jeremáyà 1:19? (16) Sọ ọ̀kan lára àwọn ìrírí àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ àdánwò tá a fi hàn nínú fídíò náà tó fún ọ níṣìírí jù lọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́