“Wá Àyè fún Un”
1 Ní àkókò kan tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó, ó sọ pé wíwà láìṣègbéyàwó jẹ́ ‘ẹ̀bùn kan.’ Lẹ́yìn náà ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.” (Mát. 19:10-12) Ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwà láìṣègbéyàwó, ó sì rọ àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tirẹ̀ nípa wíwà láìṣègbéyàwó. (1 Kọ́r. 7:7, 38) Ọ̀pọ̀ àwọn ará lónìí ló ti “wá àyè” fún wíwà láìṣègbéyàwó, tí wọ́n sì ń gbádùn àwọn àǹfààní rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní wọ̀nyí?
2 Sísin Ọlọ́run “Láìsí Ìpínyà-Ọkàn”: Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé wíwà láìṣègbéyàwó fún òun láǹfààní láti sin Jèhófà “láìsí ìpínyà-ọkàn.” Bákan náà lónìí, àwọn arákùnrin tó bá jẹ́ àpọ́n lè nàgà fún àǹfààní lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ẹni tí kò bá ṣègbéyàwó sì máa ń sábà wà lómìnira láti di aṣáájú ọ̀nà, láti kọ́ èdè àjèjì, láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù sí i, láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí láti yọ̀ǹda ara wọn fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn. Ó máa ní ọ̀pọ̀ àkókò àti àǹfààní láti máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò jíjinlẹ̀, yóò sì tún láǹfààní láti máa gba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Ẹni tí kò bá ṣègbéyàwó sábà máa ń ní ọ̀pọ̀ àkókò láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí jẹ́ fún ‘àǹfààní irú ẹni bẹ́ẹ̀.’—1 Kọ́r. 7:32-35; Ìṣe 20:35.
3 Sísin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn láwọn ọ̀nà yìí máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. Lẹ́yìn tí arábìnrin kan tí kò lọ́kọ ti lo ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, ó kọ̀wé pé: “Mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ mo sì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe! A jọ máa ń bára wa ṣe nǹkan [a sì] máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ara wa. . . . Ó ṣeé ṣe fún mi láti lo àǹfààní òmìnira tí mo ní gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lọ́kọ láti jẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí sì ti mú kí ayọ̀ mi pọ̀ sí i.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà ti ṣe tímọ́tímọ́ sí i.”
4 Lílo Àǹfààní Wíwà Láìṣègbéyàwó Lọ́nà Tó Dáa: Jésù sọ pé ohun tó yẹ kó sún ẹnì kan láti ní ẹ̀bùn wíwà láìṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ní tìtorí ìjọba ọ̀run.” (Mát. 19:12) Bó ṣe máa ń rí pẹ̀lú ẹ̀bùn èyíkéyìí, èèyàn gbọ́dọ̀ lo àǹfààní wíwà láìṣègbéyàwó dáadáa, lọ́nà tó máa fúnni láyọ̀, tó sì máa ṣeni láǹfààní. Nípa lílo àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwà láìṣègbéyàwó, àti gbígbáralé Jèhófà fún ọgbọ́n àti okun, ọ̀pọ̀ akéde tí kò ṣègbéyàwó ti rí ìjẹ́pàtàkì wíwá àyè fún ẹ̀bùn náà.