Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Kárí Ayé Láwọn Orílẹ̀-Èdè Mélòó Kan Nílẹ̀ Yúróòpù
1 Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, a mú iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sábẹ́ ìkálọ́wọ́kò láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan nílẹ̀ Yúróòpù, títí kan Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, ìkálọ́wọ́kò náà kúrò ní kékeré. Kò rọrùn láti ṣèpàdé ní gbangba, ó tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ṣeé ṣe láti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba lò fún ìpàdé. Àmọ́, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, “Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa. Àwa ti kún fún ìdùnnú.”—Sm. 126:3.
2 Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1983, àwọn aláṣẹ ò fi bẹ́ẹ̀ fi ọwọ́ líle koko mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Nígbà tó fi máa di ọdún 1989, ìjọba orílẹ̀-èdè Poland àti ti Hungary fọwọ́ sí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin. Lọ́dún 1991, a forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Látìgbà náà wá, ńṣe ni iṣẹ́ náà kàn ń tẹ̀ síwájú ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti láwọn orílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́. Láàárín March 1996 sí October 1998, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fọwọ́ sí ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín ẹyọ kan [359] ìwé tí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè mọ́kànlá nílẹ̀ Yúróòpù fi béèrè ẹ̀yáwó fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.
3 Bí o ṣe ń wo àwòrán tó wà nínú àkìbọnú yìí, ronú nípa àwọn nǹkan arabaríbí àti àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀. (Sm. 136:4) Inú rẹ á dùn láti mọ̀ pé à ń lo owó tí àwọn ará kárí ayé fi ń ṣètìlẹ́yìn dáadáa, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú ìwé Jòhánù 13:35 pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”
4 Orílẹ̀-èdè Romania, níbi tí a ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìndínlógójì bẹ̀rẹ̀ láti July 2000, wà lára àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù tó ń jàǹfààní látinú ètò tá a fi ń ran àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nípa lílo àwòrán ilé tá a ti yà kalẹ̀ fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè Ukraine kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlélọ́gọ́ta lọ́dún 2001, wọ́n sì kọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin lọ́dún 2002. Nípa lílo owó tí à ń dá sínú àpótí Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti kọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Bulgaria, Croatia, Macedonia, Moldova, Rọ́ṣíà, àti Serbia òun Montenegro.
5 Kò rọrùn rárá láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó sì ń béèrè pé kí wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó lè bẹ̀rẹ̀ ilé kíkọ́ níbẹ̀. Ìmúrasílẹ̀ yìí máa ń gba àkókò púpọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Yàtọ̀ síyẹn, iye owó tó ń parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní apá ibi tá à ń wí yìí ní ilẹ̀ Yúróòpù pọ̀ gan-an ju iye tá a máa lò lọ́pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà tàbí ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Àmọ́ ṣá o, nítorí iye àwọn olùjọsìn Jèhófà tó ń pọ̀ sí i, a ṣì nílò ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀!
6 Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu gbáà ló jẹ́ láti rí irú ìtẹ̀síwájú yíyára kánkán bẹ́ẹ̀ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí! Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ìrírí ti fi hàn, èyí ti jẹ́ ìjẹ́rìí tó jíire fún àwọn tó ń gbé láwọn àgbègbè ibi tá a ti kọ́ Gbọ̀ngàn wọ̀nyí. Láwọn ibì kan, ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí wọ́n fi hàn ní títẹ̀lé ìlànà ìkọ́lé ti wú àwọn aláṣẹ ibẹ̀ lórí lọ́pọ̀lọpọ̀.
7 Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbísí nínú ìjọsìn tòótọ́ lákòókò yìí lọ́nà tó ṣe wẹ́kú. Ọlọ́run gbẹnu wòlíì náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísá. 60:22) Dájúdájú, ẹ̀wádún tó kọjá yìí jẹ́ àkókò lójú Jèhófà pé kí ìbísí wáyé ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa bá a nìṣó ní rírọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí ìsapá wa láti mú kí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ lè máa yára kánkán sí i, bí a ti túbọ̀ ń dáwó sínú àpótí Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba! Èyí á mú ká lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀. Á túbọ̀ mú kí ìjọsìn tòótọ́ tètè gbilẹ̀ láwọn ibi púpọ̀ nílẹ̀ Yúróòpù, á sì tún jẹ́ ká lè túbọ̀ wàásù “títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 13:47.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Gbọ̀ngàn Ìjọba Alákọ̀ọ́pọ̀ Moscow, Rọ́ṣíà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4-6]
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù
Strumica, Macedonia
Daruvar, Croatia
Bitola, Macedonia
Sokal, Àgbègbè Lviv, Ukraine
Mladost, Bulgaria
Krasnooktyabrskiy, Àgbègbè Maykop, Rọ́ṣíà
Bački Petrovac, Serbia òun Montenegro
Plovdiv, Bulgaria
Tlumach, Àgbègbè Ivano-Frankivsk, Ukraine
Rava-Ruska, Àgbègbè Lviv, Ukraine
Stara Pazova, Serbia òun Montenegro
Zenica, Bosnia òun Herzegovina
Sokal, Àgbègbè Lviv, Ukraine
Zhydachiv, Àgbègbè Lviv, Ukraine