Fara Wé Ìwà Rere Jèhófà
1 Tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wo wíwọ̀ oòrùn tí ẹwà rẹ̀ fani mọ́ra tàbí tá a ṣẹ̀sẹ̀ jẹ oúnjẹ aládùn kan tán, ǹjẹ́ kì í wù wá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Orísun gbogbo ìwà rere? Ìwà rere rẹ̀ ló ń sún wa láti fara wé e. (Sm. 119:66, 68; Éfé. 5:1) Báwo la ṣe lè máa fi ànímọ́ yìí hàn?
2 Híhu Ìwà Rere sí Àwọn Aláìgbàgbọ́: Ọ̀nà kan tá a lè gbà fara wé ìwà rere Jèhófà ni nípa ṣíṣe àníyàn àtọkànwá nípa àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa. (Gál. 6:10) Fífi ìwà rere hàn ní àwọn ọ̀nà tó ṣe pàtó máa ń ní ipa rere lórí ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀rọ̀ tá à ń wàásù rẹ̀.
3 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ń dúró de dókítà ní ilé ìwòsàn kan, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin àgbàlagbà kan tó dà bíi pé òun ní àìsàn tiẹ̀ pọ̀ jù nínú gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Nígbà tó kan arákùnrin yìí láti rí dókítà, ó yọ̀ǹda kí obìnrin àgbàlagbà náà lọ rí i dípò òun. Nígbà tó yá, ó bá obìnrin náà pàdé, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí nínú ọjà ni, inú obìnrin náà sì dùn gan-an láti rí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kì í fẹ́ gbọ́ ìhìn rere náà sétí, ó sọ pé òun ti wá mọ̀ báyìí pé lóòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn. Èyí yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń lọ déédéé.
4 Híhu Ìwà Rere sí Àwọn Ará Wa: A tún ń fara wé ìwà rere Jèhófà nígbà tá a bá ń yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́. Lákòókò tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, a wà lára àwọn tó kọ́kọ́ máa ń lọ ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Irú ẹ̀mí yìí kan náà là ń fi hàn nígbà tá a bá ń ṣèrànwọ́ láti fi mọ́tò gbé àwọn ẹlòmíràn wá sí ìpàdé, tá à ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aláìlera, tá a sì ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tí a ò mọ̀ dunjú nínú ìjọ.—2 Kọ́r. 6:11-13; Héb. 13:16.
5 Ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà gbà ń fi ìwà rere hàn ni pé ó “ṣe tán láti dárí jini.” (Sm. 86:5) Ní àfarawé Jèhófà, a lè fi hàn pé a fẹ́ láti máa hu ìwà rere nípa dídárí ji àwọn ẹlòmíràn. (Éfé. 4:32) Èyí á jẹ́ kí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ‘dára, kó sì dùn.’—Sm. 133:1-3.
6 Ǹjẹ́ kí oore Jèhófà tó pọ̀ yanturu sún wa láti máa fi ìyìn fún un nígbà gbogbo, kó sì sún wa láti máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Ǹjẹ́ kí èyí sì tún sún wa láti sakun láti máa fara wé ìwà rere rẹ̀ nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.—Sm. 145:7; Jer. 31:12.