Leta Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọ̀wọ́n:
“Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.” (1 Kọ́r. 3:6) Ó mà wú wa lórí o láti rí bí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú ní Nàìjíríà! Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2003, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn ún [90,000] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a bẹ̀rẹ̀ sì ń ṣe. Èyí dára gan-an ni.
Jèhófà ń fi ìbùkún sí iṣẹ́ wa nínú ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló wà ní Nàìjíríà báyìí. Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2003, à ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan parí lọ́jọ́ iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ìpíndọ́gba. Ní báyìí, ìjọ púpọ̀ sí i ló ti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run wa.
Kí a lè pèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó fún iṣẹ́ Ìjọba náà tó ń gbilẹ̀ sí i kárí ayé, a ti ń mú kí Ilé Ìtẹ̀wé tó wà ní Oko Watchtower nítòsí ìlú Wallkill, ní New York fẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àyè tó máa fi fẹ̀ sí i fẹ́rẹ̀ẹ́ tó hẹ́kítà kan àti ààbọ̀, iṣẹ́ sì ti ń lọ gan-an lórí ẹ̀. Àyè ilẹ̀ tá à ń wí yìí fẹ̀ tó ibi tó lè gba ọgbọ̀n Gbọ̀ngàn Ìjọba alábọ́ọ́dé! A ti ṣètò bí méjì lára àgbà ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá ńlá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde yóò ṣe débẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2004. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yìí lè tẹ̀ tó ìwé ìròyìn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìṣẹ́jú àáyá kan. A ó sì tún gbé ẹ̀rọ̀ tá a ó máa lò fún ìdìwépọ̀ àtàwọn ohun èlò ìkówèéránṣẹ́ síbẹ̀ ní ọdún 2004. Èyí á mú ká lè máa tẹ ìwé púpọ̀ sí i, tá ò sì ní lò tó iye òṣìṣẹ́ tá à ń lò báyìí.
Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004 yìí, bí ẹ ṣe ń gbàdúrà làwa náà ó máa gbàdúrà pé kí Jèhófà túbọ̀ “mú kí ó máa dàgbà” sí i.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì ti Nàìjíríà