Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọ̀wọ́n:
Iṣẹ́ ribiribi là ń ṣe ká bàa lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run débi gbogbo ní Nàìjíríà. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí làwọn òṣìṣẹ́ láti orílẹ̀-èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n wá bá wa to ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wa tuntun parí iṣẹ́ lórí ẹ̀. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti dín iye òṣìṣẹ́ tó ń bá wa tẹ àwọn ìwé ìròyìn kù. Bákan náà, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí i pé ká máa tẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé àṣàrò kúkúrú tá a bá nílò ní Nàìjíríà níwọ̀n bí a ti ní ẹ̀rọ tó lè tẹ̀ ẹ́.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń rọ́ wá wo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun náà. Lára àwọn nǹkan táwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wò nínú ẹ̀rọ náà ni èyí tí wọ́n ń pè ní Quantum Pollution Control, tí kì í jẹ́ kí afẹ́fẹ́ olóró tó ń jáde lára ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà ba àyíká wa jẹ́. Lẹ́yìn tí ẹnì kan ti wo ẹ̀rọ náà, ó sọ pé: “Ibo lẹ ti rówó ra ẹ̀rọ yìí ná?” Lẹ́yìn náà ló ní kí wọ́n fi àpótí tóun lè fowó sí han òun, ó sì fowó sínú ẹ̀. Ọkùnrin náà wá sọ pé òun á máa fi kún owó tóun fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé.
Nítorí náà, tayọ̀tayọ̀ la ó fi kí yín káàbọ̀ bẹ́ ẹ bá fẹ́ wá fojú ara yín rí bá a ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹ́yìn lọ́nà rere, láti fi tẹ àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ tá a lè máa lò nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé àbẹ̀wò olóyinmọmọ ló máa já sí fún yín!
Ẹgbẹ́ àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ò mọ́wọ́ dúró, àwọn náà ti ṣe gudugudu méje. Láti ọdún márùn–ún tí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́nà yìí ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Èyí ti mú kí ohùn igbe àwọn tó ń yin Jèhófà túbọ̀ máa ròkè lálá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ìṣègùn kan ṣe sọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ṣàkíyèsí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ó sì sọ pé: “Kíkọ́ tẹ́ ẹ kọ́ Gbọ̀ngàn yìí láàárín àkókò kúkúrú jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹ ti múra ohun gbogbo sílẹ̀ dáadáa, ẹ sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Kì í wá ṣe pé èyí mú kéèyàn rí bí ilé náà ṣe bójú mu gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn nìkan ni o, àmọ́ ó tún mú kéèyàn rí báwọn tó ń jọ́sìn níbẹ̀ ṣe dáńgájíá tó, ó sì mú kéèyàn rí bí ètò tẹ́ ẹ ṣe ṣe mọ́yán lórí tó.”
A lù yín lọ́gọ ẹnu fún gbogbo iṣẹ́ ribiribi tẹ́ ẹ̀ ń ṣe nítorí àtilè mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa gbòòrò sí i! A mọrírì bẹ́ ẹ ṣe ń fínnú fíndọ̀ fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà gan-an ni o. (Òwe 3:9, 10) Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa bá a nìṣó láti rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí ìsapá gbogbo wa ká lè máa “sìn fún ìyìn ògo rẹ̀.”—Éfé. 1:12.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì ti Nàìjíríà