ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/06 ojú ìwé 1
  • Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Fífi Ìmọrírì Wo “Ilé Ọlọrun”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 9/06 ojú ìwé 1

Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọ̀wọ́n:

A dá ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀, sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2006. Alàgbà méjì, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì, akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti aṣáájú-ọ̀nà méjìlá ló wà nínú ìjọ yìí. À ń fi àkókò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin ará tẹ́ ẹ sapá láti kọ́ èdè àwọn adití torí àtilè bójú tó àwọn adití tìfẹ́tìfẹ́.

Ohun mìíràn tó fa kíki nínú ìgbòkègbodò wa lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí dá lórí àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ jáde. Láfikún sí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tá à ń tẹ̀ fúnra wa lórílẹ̀-èdè yìí fún lílò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú. Láwọn ọdún tó ti kọjá, ṣe la máa ń béèrè pé kí wọ́n bá wa kó o ránṣẹ́ láti òkè òkun, ọ̀pọ̀ ni a kì í sì í ní lọ́wọ́ látàrí ìdádúró tó máa ń wáyé lórí omi. Pẹ̀lú bá a ṣe lè ń tẹ̀ ẹ́ lábẹ́lé yìí, a nírètí pé a ó lè máa fàwọn ìwé ránṣẹ́ sí ìjọ ní gbàrà tá a bá ti rí ìwé ìbéèrè yín gbà.

Bá a ṣe ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà síwájú àti síwájú sí i. Léṣìí, tá a bá ro gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a kọ́ pọ̀, á lé ní mẹ́fà tá à ń kọ́ lọ́sẹ̀. Bákan náà, la ti parí iṣẹ́ lórí Gbọ̀ngàn Àpéjọ mẹ́rin.

Ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi, obìnrin kan tí kì í fẹ́ rí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sójú yí èrò rẹ̀ padà lẹ́yìn tó rí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn ará lákòókò tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan lọ́wọ́. Àtìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé.

Ohun tá à ń retí lọ́dọ̀ yín ni pé kẹ́ ẹ máa bá a nìṣó láti máa gbàdúrà pé kí Jèhófà máa ti ìgbòkègbodò wa yìí lẹ́yìn bá a ṣe ń retí ìgbà tí Ọlọ́run a sọ Sátánì àtàwọn iṣẹ́ burúkú ọwọ́ rẹ̀ di òfo láìpẹ́ láìjìnnà nípasẹ̀ ‘ẹni náà tó jókòó lórí ẹṣin funfun,’ ìyẹn Jésù Kristi.—1 Jòh 3:8; Ìṣí. 6:2.

Àwa arákùnrin yín,

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì ti Nàìjíríà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́