ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/07 ojú ìwé 1
  • Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Wọ́n Ra Ilé Iṣẹ́ Àkọ́kọ́
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 9/07 ojú ìwé 1

Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ẹ̀yin Akéde Ọ̀wọ́n:

A láyọ̀ láti rí ibi tí iṣẹ́ wa tẹ̀ síwájú dé láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà lábẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2007! Ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń múni lọ́kàn yọ̀ la ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ní báyìí, iṣẹ́ ti parí lórí ọ́fíìsì tuntun tá à ń kọ́ sílùú Èkó. Èyí á sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti máa bójú tó ọ̀pọ̀ ohun tó yẹ. Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàtúnṣe sí ọ́fíìsì àtijọ́ tá à ń lò ní Èkó ká lè sọ ọ́ di ibi tá a ó ti máa ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. A nírètí pé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2008 ni ilé ẹ̀kọ́ náà máa bẹ̀rẹ̀.

Ìròyìn Ìjọba No. 37, “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” tá a pín jákèjádò ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lórílẹ̀-èdè yìí lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà márùn-ún. Lẹ́yìn tí arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ kan gba Ìròyìn Ìjọba No. 37 tó sì kà á, ńṣe ni oorun dá wáí lójú ẹ̀. Lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, ó lọ sípàdé ó sì ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn míì tí Ìròyìn Ìjọba yẹn wọ̀ lọ́kàn kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n ń fẹ́ ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!, wọ́n sì ń fẹ́ ẹni tá á wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

Ìdí tá a fi pín Ìròyìn Ìjọba No. 37 lọ́nà yìí ni láti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. (Mát. 28:19, 20) Bó o ti ń wàásù, má gbà gbé láti kíyè sí àwọn tó bá fìfẹ́ hàn, kó o sì padà lọ torí àtilè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú wa dùn láti máa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú yín nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì yìí. A nífẹ̀ẹ́ yín gan-an ni.

Àwa arákùnrin yín,

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Nàìjíríà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́