Bí A Ṣe Lè Wà ní Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
1. Òye wo ni arábìnrin kan wá ní nípa àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí rẹ̀?
1 Arábìnrin kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé ṣe ni mo kàn wà nínú òtítọ́ ṣáá fún 20 ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí mo ti wà níbẹ̀, nípa wíwulẹ̀ lọ sí ìpàdé àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.” Àmọ́ ṣá o, ó wá fi kún un pé: “Mo ti wá dé ìparí èrò pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe pàtàkì, àwọn nìkan kò lè mú mi dúró nígbà tí nǹkan bá bẹ̀rẹ̀ sí nira. . . . Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé mo gbọ́dọ̀ yí ìrònú mi padà, kí n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó nítumọ̀, kí n bàa lè mọ Jèhófà dáradára, kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí n sì mọrírì ohun tí Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa.”
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti wà ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà?
2 Níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà gba ìsapá gan-an ni. Kò mọ sórí wíwulẹ̀ kópa déédéé nínú ìgbòkègbodò Kristẹni. Bí a kì í bá gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, bó bá yá ńṣe ló máa dà bí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ nígbà kan rí tó ti pẹ́ tá a ti ríra gbẹ̀yìn. (Ìṣí. 2:4) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.—Sm. 25:14.
3. Ọ̀nà wo la lè máa gbà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò fi ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
3 Àdúrà àti Àṣàrò Ṣe Kókó: Ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé ọkàn-àyà ró kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn fífa ìlà sídìí àwọn kókó pàtàkì tá a bá rí nínú ìwé táà ń kà tàbí ká wulẹ̀ máa wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ. Ohun tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí ni pé ká máa ronú lórí ohun tí ìsọfúnni náà ń ṣí payá fún wa nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà, àwọn ìlànà rẹ̀ àti ànímọ́ rẹ̀. (Ẹ́kís. 33:13) Lílóye àwọn nǹkan tẹ̀mí máa ń nípa gan-an lórí ìmọ̀lára wa, ó sì máa ń sún wa láti ronú nípa ìgbésí ayé wa. (Sm. 119:35, 111) Ohun tó yẹ ká máa ní lọ́kàn nígbà tí a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ni pé a fẹ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Ják. 4:8) Ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ṣe tọkàntọkàn máa ń gba àkókò, ó sì yẹ ká ṣe é níbi tó dára fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ká tó lè ṣe irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ déédéé, ó ń béèrè fún ìkóra-ẹni-níjàánu. (Dán. 6:10) Ká tiẹ̀ ní ọwọ́ rẹ máa ń dí gan-an, ǹjẹ́ ò ń ya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà?—Sm. 119:147, 148; 143:5.
4. Báwo ni gbígbàdúrà ká tó bẹ̀rẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà?
4 Ọ̀kan pàtàkì ni àdúrà àtọkànwá jẹ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó nítumọ̀. Kí òtítọ́ Bíbélì tó lè nípa lórí ọkàn-àyà wa kí wọ́n sì sún wa láti máa “ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀,” a nílò ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Héb. 12:28) Nítorí náà, ó pọn dandan pé ká máa bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí Jèhófà ká tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí. (Mát. 5:3) Bí a ti ń ronú lórí Ìwé Mímọ́ tí a sì ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ètò àjọ Jèhófà mú jáde, bẹ́ẹ̀ là ń ṣí ọkàn-àyà wa payá fún Jèhófà. (Sm. 62:8) Kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí jẹ́ ọ̀nà kan táà ń gbà jọ́sìn láti fi ìfọkànsìn wa sí Jèhófà hàn, ká sì mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ sí i.—Júúdà 20, 21.
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́?
5 Bó ṣe máa ń rí nínú gbogbo àjọṣe, a gbọ́dọ̀ máa sọ àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà dọ̀tun déédéé kó má bàa bà jẹ́ ní gbogbo ìgbà tí a bá fi wà láàyè. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa wá àkókò lójoojúmọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, bí a ti mọ̀ pé, ìyẹn á mú kí òun náà sún mọ́ wa.—Sm. 1:2, 3; Éfé. 5:15, 16.