ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/04 ojú ìwé 7
  • Lílọ Sípàdé Déédéé—Ohun Tó Yẹ Kó Gbapò Iwájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílọ Sípàdé Déédéé—Ohun Tó Yẹ Kó Gbapò Iwájú
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rí i Dájú Pé O Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Àwọn Ìpàdé Ìjọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 3/04 ojú ìwé 7

Lílọ Sípàdé Déédéé—Ohun Tó Yẹ Kó Gbapò Iwájú

1 Àwọn ìdílé Kristẹni máa ń fi lílọ sípàdé ìjọ déédéé sípò iwájú. Àmọ́, àwọn ohun àìgbọdọ̀máṣe ìgbésí ayé lóde òní lè máà jẹ́ kí èyí rọrùn láti ṣe. Ǹjẹ́ iṣẹ́ ilé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí gbà lára àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn Jèhófà? Bí a bá ń wo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi àwọn ohun tó yẹ sí ipò àkọ́kọ́.—1 Sám. 24:6; 26:11.

2 Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí Jèhófà fẹ́, ó lọ ṣa igi lọ́jọ́ Sábáàtì. Ó lè máa rò pé ńṣe lòun fẹ́ pèsè fún ìdílé òun tàbí pé ohun tí òun ṣe kò tó nǹkan. Àmọ́, Jèhófà lo ìdájọ́ tí a ṣe fún ọkùnrin náà láti fi hàn pé ṣíṣe àwọn nǹkan tara lákòókò tó yẹ ká fi ṣe ìjọsìn kì í ṣe ohun tá à ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú.—Núm. 15:32-36.

3 Kíkojú Ìṣòro Náà: Ìjàkadì gidi ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ará láti má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ dí wọn lọ́wọ́ ìpàdé ìjọ. Àwọn kan ti kojú ìṣòro yìí nípa bíbá ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, nípa ṣíṣètò pé kí àwọn àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn máa bára wọn ṣe pàṣípààrọ̀ àkókò iṣẹ́ wọn, nípa wíwá iṣẹ́ tó máa túbọ̀ bá ipò wọn mu tàbí nípa ṣíṣàì fi àwọn ohun tí kò pọn dandan nígbèésí ayé dí ara wọn lọ́wọ́. Ó dájú gbangba pé ṣíṣe irú àwọn ohun tí kò rọrùn bẹ́ẹ̀ nítorí ìjọsìn tòótọ́ ń mú inú Ọlọ́run dùn gidigidi.—Héb. 13:16.

4 Iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tún lè jẹ́ ìṣòro kan. Ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Mo máa ń ṣe díẹ̀ lára iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ mi ṣáájú ìpàdé, màá sì wá ṣe ìyókù tí mo bá padà délé.” Nígbà táwọn òbí kan rí i pé kì í ṣeé ṣe fáwọn ọmọ láti parí gbogbo iṣẹ́ àṣetiléwá wọn láwọn ọjọ́ ìpàdé, wọ́n lọ ṣàlàyé fáwọn olùkọ́ pé lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ ohun tó gbapò iwájú nínú ìdílé àwọn.

5 Ètò tó ṣe gúnmọ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo ìdílé lápapọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ilé kí wọ́n lè múra sílẹ̀ láti tètè dé sí ìpàdé. (Òwe 20:18) Àní, a lè kọ́ àwọn ògowẹẹrẹ pàápàá láti máa wọṣọ fúnra wọn, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ìpàdé ní àkókò kan pàtó. Àwọn òbí lè fi àpẹẹrẹ tiwọn gbin ìjẹ́pàtàkì ìpàdé sí ọkàn àwọn ọmọ wọn.—Òwe 20:7.

6 Bí pákáǹleke ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń pọ̀ sí i, ó ṣe pàtàkì pé ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé. Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa wo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó, ká sì máa fi lílọ sí ìpàdé déédéé sí ipò iwájú.—Héb. 10:24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́