Ẹ Máa Fọpẹ́ Hàn
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. (2 Tím. 3:1) Ní pàtàkì jù lọ, ó yẹ ká dúpẹ́ fún ẹ̀bùn iyebíye tó fún wa, ìyẹn ni Ọmọ rẹ̀ tó kú nítorí tiwa. (Jòh. 3:16) Síwájú sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi tẹ̀mí ń pa àwọn tó wà nínú ìsìn èké, àwa ń gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí. (Aísá. 65:13) A wà nínú ẹgbẹ́ ará kan tó kárí ayé, a sì láǹfààní láti máa kópa nínú mímú kí ìjọsìn tòótọ́ gbilẹ̀, èyí tó ń fúnni láyọ̀. (Aísá. 2:3, 4; 60:4-10, 22) Báwo la ṣe lè máa fọpẹ́ hàn sí Jèhófà nítorí ọ̀pọ̀ ìbùkún tó ń fún wa?—Kól. 3:15, 17.
2 Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Tayọ̀tayọ̀ àti Tọkàntọkàn: Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa fífúnni láwọn ohun ìní tara, ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́r. 9:7) Ìlànà yìí náà kan iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Ọpẹ́ wa ń hàn nínú ìtara wa fún òtítọ́, ayọ̀ wa ní ìpàdé Kristẹni, ìtara wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ayọ̀ wa nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sm. 107:21, 22; 119:14; 122:1; Róòmù 12:8, 11.
3 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Òfin kò sọ iye ohun pàtó téèyàn lè mú wá fún àwọn ìrúbọ kan. Olùjọsìn kọ̀ọ̀kan lè fọpẹ́ hàn nípa ṣíṣe ìtọrẹ “ní ìwọ̀n ìbùkún Jèhófà” tó ti rí gbà. (Diu. 16:16, 17) Bákan náà lónìí, ọkàn tó kún fún ìmọrírì yóò sún wa láti ṣe gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Tí àwọn kan bá wà ní àkókò ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nílé ẹ̀kọ́, wọ́n máa ń lo àǹfààní yẹn láti fi túbọ̀ lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn, kódà wọ́n fi ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ kópa púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn láwọn àkókò wọ̀nyẹn?
4 Mímú Kí Ọpẹ́ Wa Pọ̀ Gidigidi: Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi ọpẹ́ wa hàn sí Jèhófà ni nígbà tá a bá ń gbàdúrà. (1 Tẹs. 5:17, 18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa “kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.” (Kól. 2:7) Kódà nígbà tí ọwọ́ wa bá dí gan-an tàbí tá a bá wà nínú másùnmáwo, ó yẹ ká máa fi ìdúpẹ́ kún àwọn àdúrà wa ojoojúmọ́. (Fílí. 4:6) Bẹ́ẹ̀ ni o, nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti àdúrà wa, ẹ jẹ́ kí a “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.”—2 Kọ́r. 9:12.