ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/04 ojú ìwé 1
  • Fi Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ṣe Àwòkọ́ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ṣe Àwòkọ́ṣe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà—Orísun Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jehofa Olùfẹ́ Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 7/04 ojú ìwé 1

Fi Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ṣe Àwòkọ́ṣe

1 “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sm. 37:28) Nítorí ìdí èyí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sọ pé òun máa pa ayé aláìṣòdodo yìí run, ó ti ṣètò pé ká kọ́kọ́ ṣe ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn. (Máàkù 13:10) Èyí á fún àwọn èèyàn láǹfààní láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (2 Pét. 3:9) Ǹjẹ́ à ń sapá láti fi ìdájọ́ òdodo Jèhófà ṣe àwòkọ́ṣe? Ǹjẹ́ ìpọ́njú àti ìrora tó ń bá ẹ̀dá èèyàn fínra ń sún wa láti lọ sọ ìrètí Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn? (Òwe 3:27) Bá a bá nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, a óò fẹ́ láti fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.

2 Máa Wàásù Láìṣe Ojúsàájú: Bá a bá ń polongo ète Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn láìsí pé à ń ṣe ojúsàájú, ó fi hàn pé à ń “ṣe ìdájọ́ òdodo.” (Míkà 6:8) A ò gbọ́dọ̀ ní ìṣarasíhùwà kan tí ẹ̀dá aláìpé sábà máa ń ní, ìyẹn fífi ìrísí àwọn èèyàn ṣèdájọ́ wọn. (Ják. 2:1-4, 9) Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́ lè mú káwọn èèyàn ṣe ìyípadà kíkàmàmà nínú ìgbésí ayé wọn. (Héb. 4:12) Mímọ èyí lè sún wa láti lọ fi ìgboyà wàásù fáwọn èèyàn, kódà àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀ níṣàájú.

3 Arábìnrin wa kan ń tajà ní ṣọ́ọ̀bù kan, àmọ́ ìrísí ọkùnrin kan tó máa ń wá rajà níbẹ̀ máa ń dẹ́rù bà á. Síbẹ̀, nígbà kan tí àyè rẹ̀ yọ, ó gbìyànjú láti wàásù fún un nípa ìlérí Ọlọ́run láti sọ ayé di Párádísè. Ọkùnrin náà fi ìkanra dáhùn pé òun ò nígbàgbọ́ nínú ìtàn àgbọ́sọ, àti pé abẹ́gbẹ́yodì lòun, òun sì máa ń lo oògùn olóró. Ṣùgbọ́n, arábìnrin wa kò juwọ́ sílẹ̀ o. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ló rò nípa irun gígùn tí òun ní, arábìnrin náà sì fi ọgbọ́n ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí fún un. (1 Kọ́r. 11:14) Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un pé lọ́jọ́ kejì, ọkùnrin náà ti fá gbogbo irùngbọ̀n rẹ̀ ó sì ti gé irun orí rẹ̀ mọ́lẹ̀! Èyí múnú arábìnrin wa dùn gan-an. Nígbà tó lóun fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, arábìnrin náà ṣètò fún èyí, arákùnrin kan sì gbà láti máa bá a ṣe é. Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ síwájú gan-an títí tó fi ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Bíi ti ọkùnrin yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sin Jèhófà lónìí dúpẹ́ pé àwọn tó wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run fún wọn kò ṣe ojúsàájú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò káàárẹ̀ nínú ìsapá wọn.

4 Láìpẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí gbogbo àìṣòdodo tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (2 Pét. 3:10, 13) Níwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù yìí, ẹ jẹ́ ká fi ìdájọ́ òdodo Jèhófà ṣe àwòkọ́ṣe nípa fífún gbogbo èèyàn láǹfààní láti lè mórí bọ́ nínú ìparun tó ń bọ̀ lórí ayé aláìṣòdodo tí Sátánì ń ṣàkóso yìí.—1 Jòh. 2:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́