Ìfaradà Lérè
1 “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Gbólóhùn yìí, tá a mú látinú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” jẹ́ kó yé wa kedere pé bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ oníwà títọ́, a gbọ́dọ̀ múra tán láti fojú winá ọ̀pọ̀ àdánwò. Ṣùgbọ́n tí olúkúlùkù wa bá gbára lé okun Jèhófà, a ó lè “fara dà á dé òpin,” a ó sì rí ‘ìgbàlà.’—Mát. 24:3, 13; Fílí. 4:13.
2 Inúnibíni, àìsàn, ìṣòro owó àti ìrora ọkàn lè mú kí nǹkan máa nira fún wa gan-an lójoojúmọ́. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé Sátánì ò fìgbà kan juwọ́ sílẹ̀ nínú ìsapá rẹ̀ láti jin ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà lẹ́sẹ̀. Bá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Baba wa ọ̀run nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́, à ń jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba pé onírọ́ ni Èṣù tí ń ṣáátá Ọlọ́run, tó ń sọ pé a ò ní jẹ́ oníwà títọ́. Ó mà ń fini lọ́kàn balẹ̀ o láti mọ̀ pé Ọlọ́run ń rí “omijé” wa nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro! Omijé wa yìí ṣeyebíye lójú Jèhófà, ìwà títọ́ wa sì ń múnú rẹ̀ dùn!—Sm. 56:8; Òwe 27:11.
3 Àdánwò Ń Yọ́ Wa Mọ́: Ìpọ́njú lè jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa ò lágbára mọ́ tàbí pé a ní àléébù kan, irú bí ìgbéraga tàbí àìnísùúrù. Dípò ká máa gbìyànjú láti yẹra fún àdánwò tàbí láti fòpin sí i nípa ṣíṣe àwọn ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, a ní láti fiyè sí ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sọ pé ká “jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré.” Kí nìdí? Nítorí pé tá a bá fi ìṣòtítọ́ fara da àdánwò, a ó lè “pé pérépéré, [a ó sì] yè kooro ní gbogbo ọ̀nà.” (Ják. 1:2-4) Ìfaradà lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye, irú bí ìfòyebánilò, ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti àánú.—Róòmù 12:15.
4 Ìjójúlówó Ìgbàgbọ́ Wa Ni A Óò Dán Wò: Nígbà tá a bá fara da àdánwò, ìgbàgbọ́ wa yóò di èyí tá a ti dán ìjójúlówó rẹ̀ wò, ìyẹn sì níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run. (1 Pét. 1:6, 7) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú ká dúró gbọn-in nígbà ìṣòro lọ́jọ́ iwájú. Síwájú sí i, a ó mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá, èyí á sì jẹ́ kí ìrètí wa lágbára, kó sì túbọ̀ dá wa lójú sí i.—Róòmù 5:3-5.
5 Jákọ́bù orí kìíní ẹsẹ̀ kejìlá sọ èrè gíga jù lọ tá a lè rí jẹ nítorí ìfaradà, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè.” Nítorí náà, ká má ṣe jáwọ́ láé nínú ìfọkànsìn wa sí Jèhófà, ká lọ fọkàn balẹ̀ pé yóò rọ̀jò ìbùkún sórí “àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”