A Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà
Tó o bá gbọ́ orúkọ àwọn èèyàn ìgbàanì bíi Kórà, Dátánì àti Ábírámù, kí lohun tó máa wá sí ọ lọ́kàn? Ẹ̀mí ọ̀tẹ̀! Kí ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí? Ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ni. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìwà búburú tí wọ́n hù àti àbájáde rẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Númérì orí kẹrìndínlógún, àkópọ̀ ìtàn yìí sì wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Fi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba fún Ọlá Àṣẹ Ọlọ́run,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2002. Wàá jàǹfààní gan-an tó o bá ka àpilẹ̀kọ yìí, tó o sì tún wo bí fídíò náà, Respect Jehovah’s Authority, ṣe ṣí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ payá lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀. Wàá rí àríyànjiyàn ńlá tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Kórà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti bàbá wọn tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀, ẹni tó ń bá Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run jà. (Núm. 26:9-11) Ó yẹ kí ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ yìí ta gbogbo wa jí ká lè túbọ̀ máa fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà.
Bó o ṣe ń wo fídíò yìí, kíyè sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Kórà àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ kò jẹ́ adúróṣinṣin ní ọ̀nà pàtàkì mẹ́fà : (1) Báwo ni wọ́n ṣe kùnà láti bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀? (2) Báwo ni wọ́n ṣe jẹ́ kí ìgbéraga, fífi ìwàǹwára wá ipò ọlá àti owú jíjẹ́ nípa lórí wọn? (3) Báwo ni wọ́n ṣe ń ránnu mọ́ àléébù àwọn tí Jèhófà yàn? (4) Kí ni wọ́n ń ráhùn lé lórí? (5) Kí nìdí táwọn àǹfààní àkànṣe tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kò fi tẹ́ wọn lọ́rùn mọ́? (6) Báwo ni wọ́n ṣe fi ìdúróṣinṣin sí àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti ìdílé wọn ṣáájú ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run?
Wo báwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ inú Bíbélì yìí ṣe kan ọ̀nà tí àwa náà ń gbà wo ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lónìí: (1) Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe nínú ìjọ, kí sì nìdí? (2) Báwo la ṣe lè borí èròkerò tó bá wà lọ́kàn wa? (3) Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí àìpé àwọn tí Jèhófà yàn láti jẹ́ aṣáájú? (4) Kí ló yẹ ká ṣe bá a bá kíyè sí i pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ẹ̀mí ìráhùn? (5) Ojú wo ló yẹ ká fi wo àǹfààní èyíkéyìí tá a bá rí gbà nínú ètò àjọ Ọlọ́run? (6) Àwọn wo ni a kò gbọ́dọ̀ fi ṣáájú ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run, ìgbà wo lèyí sì lè jẹ́ ìdánwò líle fún wa?
Lẹ́yìn tá a ti gbé ìtàn yìí yẹ̀ wò nínú ìjọ, o ò ṣe tún fídíò yìí wò? Jẹ́ kí fídíò yìí túbọ̀ tẹ àwọn ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Jèhófà mọ́ ọ lọ́kàn dáadáa!—Sm. 18:25; 37:28.