ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/05 ojú ìwé 1
  • Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Wàásù Nìṣó!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Ẹ Yin Orúkọ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 4/05 ojú ìwé 1

Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù

1 Àsìkò tó le koko là ń gbé báyìí. Ogun abẹ́lé, ìjà ẹ̀yà ìran, ìjábá, àtàwọn àjálù burúkú mìíràn ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé. Àsìkò tá a wà báyìí ló ṣe pàtàkì jù lọ fáwọn èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn ò ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì. Láwọn ibì kan, ó lè má rọrùn láti bá àwọn èèyàn nílé, kódà ó tiẹ̀ tún lè ṣòro jù bẹ́ẹ̀ lọ láti rẹ́ni tó máa fetí sílẹ̀ tàbí tó máa nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ṣe wù kó rí, ó ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí.—Mát. 24:14.

2 Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn: Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń fi ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn hàn. “Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9; Ìsík. 33:11) Ó pàṣẹ pé ká wàásù, ìdí nìyẹn tí Jésù ṣe sọ pé “a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Ọlọ́run ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n tọ òun wá kí ìdájọ́ tó ń bọ̀ sórí ayé Sátánì yìí má bàa kàn wọ́n. (Jóẹ́lì 2:28, 29, 32; Sef. 2:2, 3) Ṣé kò yẹ ká dúpẹ́ pé Jèhófà pín àǹfààní yẹn kàn wá?—1 Tím. 1:12, 13.

3 Ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé ti ọdún 2004 fi hàn pé lóṣooṣù, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ẹ̀tàdínláàádọ́rùn-ún [6,085,387] là ń ṣe ní ìpíndọ́gba, a sì ń batisí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ọmọ ẹ̀yìn tuntun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá táwọn akéde kan ṣe láti lè tẹra mọ́ bíbá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn ló jẹ́ ká lè rí àwọn kan lára àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ yìí. Ẹ ò rí i pé ayọ̀ ńlá nìyẹn sì jẹ́ fáwọn ará, nítorí pé àǹfààní tí ò láfiwé ni láti wà lára àwọn tó ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí!—1 Kọ́r. 3:5, 6, 9.

4 Máa Yin Orúkọ Ọlọ́run: À ń tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ká lè máa yin Jèhófà ní gbangba ká sì lè máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ níwájú gbogbo èèyàn. (Héb 13:15) Sátánì ti ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà” kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ò lágbára láti tán ìṣòro àwọn èèyàn, pé kò bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn tàbí pé kò tiẹ̀ sẹ́ni tó ń jẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣí. 12:9) Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe la fi ń gbèjà òtítọ́ nípa ọlá ńlá Baba wa ọ̀run, ẹ jẹ́ ká máa yin orúkọ rẹ̀ nìṣó títí láé.—Sm. 145:1, 2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́