Ẹ Máa Gbé Ara Yín Ró
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sa gbogbo ipá rẹ̀ kó bàa lè fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lókun. (Ìṣe 14:19-22) Àwa pẹ̀lú máa ń ṣàníyàn gidigidi bá a bá gbọ́ pé àwọn arákùnrin wa ń dojú kọ ipò tó le koko, a sì máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíbélì fi hàn pé gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan. (Róòmù 15:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tá a lè máa gbà ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 Tẹs. 5:11.
2 Fòye Mọ Ohun Táwọn Ẹlòmíì Nílò: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ròyìn pé Dọ́káàsì, “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” (Ìṣe 9:36, 39) Ó máa ń ṣàkíyèsí àwọn tó ṣaláìní ó sì máa ń ṣe ohun tí ipá rẹ̀ ká láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ àtàtà ló fi lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé o! Bóyá o rí i pé àgbàlagbà kan ń fẹ́ ẹni táá máa gbé òun wá sí ìpàdé. Tàbí kó o mọ aṣáájú ọ̀nà kan tí kì í rẹ́ni bá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀, pàápàá lọ́sàn-án. Bó o bá rí i pé ẹnì kan ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lọ́nà yìí, tó o sì ṣe ohun tí agbára rẹ ká láti ràn án lọ́wọ́, wo bí orí á ṣe yá onítọ̀hún tó!
3 Máa Jíròrò Nǹkan Tẹ̀mí: A tún lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa gbé àwọn ẹlòmíràn ró. (Éfé. 4:29) Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ sọ pé: “Bó o bá fẹ́ máa gbéni ró, máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan tí ń gbéni ró, o lè lo ìbéèrè kékeré, irú bíi, ‘Báwo lo ṣe rí òtítọ́?’” Fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ. Fi hàn pé ò ń ro tàwọn tó rẹ̀wẹ̀sì àtàwọn tó ṣeé ṣe kójú máa tì. (Òwe 12:25) Má ṣe jẹ́ kí jíjíròrò nípa eré ìnàjú inú ayé gba àkókò tó yẹ kí ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni fi máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí.—Róòmù 1:11, 12.
4 Àmọ́, àwọn nǹkan wo gan-an lo lè máa sọ tí wàá fi máa gbé àwọn mìíràn ró? Nígbà tó ò ń ka Bíbélì tàbí tó ò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ǹjẹ́ o rí ìlànà kan tó mú kí ìmọrírì tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ sí i? Ǹjẹ́ ohun kan tó o gbọ́ nínú àsọyé fún gbogbo ènìyàn tàbí èyí tó o gbọ́ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin? Àbí ìrírí kan tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró tó o gbọ́ ló wú ọ lórí gan-an? Bó o bá ka àwọn ohun iyebíye tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ sí pàtàkì, gbogbo ìgbà ni wàá máa rí ohun kan tí ń gbéni ró sọ fáwọn ẹlòmíràn.—Òwe 2:1; Lúùkù 6:45.
5 Bá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tá ò sì máa fẹnu wa sọ bótobòto, ó dájú pé a óò máa gbé ara wa ró.—Òwe 12:18.