ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/05 ojú ìwé 1
  • Ẹ Polongo Ògo Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Polongo Ògo Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.”—Sáàmù 96:8.
    “Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.”—Sáàmù 96:8.
  • Ẹ Máa Yin Jèhófà Lógo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 11/05 ojú ìwé 1

Ẹ Polongo Ògo Jèhófà

1 Onísáàmù náà polongo pé: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé. Ẹ máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.” Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, èyí tó ń ṣe lọ́wọ́ àtèyí tó ṣì máa ṣe, ó ń wù wá látọkàn wá pé ká máa polongo ògo rẹ̀!—Sm. 96:1, 3.

2 Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run ká sì máa yìn ín ní gbangba jákèjádò ayé. (Mál. 1:11) Ẹ ẹ̀ rí i pé ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló wà láàárín wa àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì tí wọ́n ń lò! Iṣẹ́ sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ yìí ti wá di kánjúkánjú báyìí níwọ̀n bó ti jẹ́ pé dandan ni káwọn èèyàn fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ náà kí wọ́n tó lè la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já. (Róòmù 10:13-15) Bákan náà, bí àlàáfíà bá máa wà káàkiri ayé, àní bó bá máa wà láàárín àwọn tó ń gbé láyé, ó di dandan kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Ní tòdodo, gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló rọ̀ mọ́ orúkọ rẹ̀.

3 “Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi.” Ṣùgbọ́n káwọn èèyàn tó lè “gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un,” wọ́n gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́ nípa rẹ̀. (Sm. 96:4, 8) Síbẹ̀, àwọn kan ṣì ń sọ pé kò sí Ọlọ́run. (Sm. 14:1) Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé kò ní agbára olóókan tàbí kẹ̀, kó jẹ́ pé kò mú ọ̀ràn ọmọ ẹ̀dá ní ọ̀kúnkúndùn. Bá a ṣe ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ẹlẹ́dàá wa, àwọn nǹkan tó fẹ́ gbé ṣe, àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fífanimọ́ra, ńṣe là ń kókìkí Jèhófà.

4 Nínú Ìwà Wa: Bá a bá ń fi àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ṣèwà hù, ṣe là ń bọ̀wọ̀ fún un. Kì í sì í gbójú fo ìwà rere wa dá. (1 Pét. 2:12) Bí àpẹẹrẹ, ìmúra wa tó mọ́ àti ìrísí wa tó dùn ún wò lè mú káwọn èèyàn máa sọ ohun tó dáa nípa wa ó sì lè jẹ́ àǹfààní láti sọ fún wọn nípa èrè tó wà nínú kéèyàn máa tẹ̀lé àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tím. 2:9, 10) Ìyẹn layọ̀ wa ṣe máa ń kún nígbà táwọn èèyàn bá rí ‘àwọn iṣẹ́ àtàtà wa, tí wọ́n sì ń fi ògo fún Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run’!—Mát. 5:16.

5 Nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe wa, ẹ jẹ́ ká máa kókìkí ọláńlá Ọlọ́run wa lójoojúmọ́ ká bàa lè máa jẹ́ ìpè ayọ̀ náà pé: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Sm. 96:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́