ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/05 ojú ìwé 8
  • Ohun Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Ṣe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Máa Fi Ìháragàgà Polongo Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Báwo Lo Ṣe Lè Máa Fi Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù Lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Má Ṣe Fi Iṣẹ́ Ìwàásù Falẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 11/05 ojú ìwé 8

Ohun Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Ṣe

1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ìhà wo làwọn èèyàn sì máa ń kọ sí iṣẹ́ náà?

1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn Kristẹni ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun bí wọ́n ti ń tọ́wọ̀ọ́rìn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (2 Kọ́r. 2:14-16) Bá a bá ṣe ń tan ìmọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀ sí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á ṣe máa dà bí òórùn dídùn atura sí Jèhófà. Báwọn kan ṣe ń nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere náà làwọn kan kì í fẹ́ gbọ́. Ṣùgbọ́n torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ wa ò já mọ́ nǹkan kan. Ẹ jẹ́ ká yẹ̀ ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń ṣe wò.

2. Kí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń jẹ́ ká lè fi hàn?

2 Ó Ń Gbé Jèhófà Ga: Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé torí nǹkan tí Jèhófà ń ṣe fún wa la ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 1:9-11) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ táwa Kristẹni ń ṣe ló ń jẹ́ ká láǹfààní láti lè fi hàn pé ojúlówó ni ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ akéde máa ń tẹ̀lé àṣẹ tí Bíbélì pa fún wa pé ká máa wàásù ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn láìfi bí ipò nǹkan ṣe le sí fún wọn pè tàbí láìka ti àìfẹ́ẹ́gbọ́ àwọn èèyàn sí. Jíjẹ́ adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn!—Òwe 27:11.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì púpọ̀ pé ká máa bá a lọ láti sọ orúkọ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn?

3 Láfikún sí ìyẹn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní ipa tó ń kó nínú mímú kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe. Jèhófà sọ nípa ìparun tó máa dé bá ayé Sátánì yìí pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 39:7) Bí àwọn orílẹ̀-èdè yóò bá mọ̀ pé òun ni Jèhófà, ó pọn dandan pé káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa bá a lọ láti máa polongo orúkọ rẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.”—Ìṣí. 14:6, 7.

4. Báwo ni ìdájọ́ ṣe máa dá lé iṣẹ́ ìwàásù lórí?

4 Orí Ẹ̀ Ni Ìdájọ́ Máa Dá Lé: Ìwàásù ìhìn rere tún máa wà lára ohun tí ìdájọ́ máa dá lé lórí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Kristi Jésù máa gbẹ̀san lára “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹs. 1:8, 9) Ìhà tí kálukú bá kọ sí ìhìn rere lá pinnu irú ìdájọ́ tó máa tọ́ sí i. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí gbé lé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run léjìká! Ká má bàa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń gbẹ̀mí là yìí fáwọn èèyàn.—Ìṣe 20:26, 27.

5. Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń nawọ́ àánú rẹ̀ sáwọn èèyàn?

5 Bá a ṣe ń bá a lọ láti máa ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ojúure Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń nawọ́ àánú rẹ̀ sí wọn. (1 Tím. 2:3, 4) Nítorí pé a mọ̀ pé ìgbésí ayé àwọn èèyàn máa ń yí padà lóòrèkóòrè, ó yẹ ká máa padà lọ sọ́dọ̀ wọn ká sì máa rọ̀ wọ́n láti wá Jèhófà kó tó pẹ́ jù. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run wa” hàn, ẹni tí “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—Lúùkù 1:78; 2 Pét. 3:9.

6. Ọ̀nà wo ni dídí tí ọwọ́ wa ń dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà gbà ń ṣe wá lóore?

6 Bó Ṣe Ń Ṣe Àwa Alára Lóore: Ààbò ni dídí tí ọwọ́ wa máa ń dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ fún wa. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ‘ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ ká sì má ṣe jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan burúkú yìí sọ wá di ẹlẹ́gbin. (2 Pét. 3:11-14; Títù 2:11, 12) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí á ‘fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, kí á di aláìṣeéṣínípò, kí á máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa,’ ní mímọ̀ pé òpò wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kì í ṣe asán.—1 Kọ́r. 15:58.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́