Ẹ̀kọ́ Tó Máa Jẹ́ Ká Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
1 Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún wa bá a ṣe ń rí i pé báwọn èèyàn ṣe ń lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú kí inú wọn dùn! Ó ṣe kedere pé ara wa máa ń yá gágá nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn ní ìmọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3
2 Kí Ló Mú Kó Dára Jù Lọ: Gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe làwọn èèyàn ń gbà láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lóde òní, ó sì máa ń jẹ́ lórí gbogbo nǹkan téèyàn lè ronú kàn. (Oníw. 12:12) Ó kàn jẹ́ pé irú ìmọ̀ yẹn ó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” ni. (Ìṣe 2:11) Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ tí ayé ń kọ́ni yìí tíì lè mú káwọn èèyàn sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wọn kí wọ́n sì mọ ohun tó fẹ́ ṣe? Ṣó ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun táá ṣẹlẹ̀ tá a bá kú tàbí ohun tó fà á tá a fi ń jìyà tó báyìí? Ìrètí wo ló ti fún aráyé? Ṣó ti mú kí ìdílé kóówá wà lálàáfíà? Kó sóhun tó jọ ọ́. Lẹ́yìn kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kò sí ibòmíì tá a ti lè rí ìdáhùn gidi sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.
3 Ohun tí aráyé nílò àmọ́ tó ṣọ̀wọ́n nínú ayé tá a wà yìí ni ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fúnni, nǹkan ọ̀hún sì ni ìwà ọmọlúwàbí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fa kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, èrò pé ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tu pátápátá kúrò lọ́kàn àwọn tó bá gbà á gbọ́ tí wọ́n sì fi ń ṣèwà hù. (Héb. 4: 12) Ó ti jẹ́ káwọn èèyàn pa onírúurú ìwà jàgídíjàgan tì kí wọ́n sì fi ‘àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara wọn láṣọ.’ (Kól. 3:9-11; Míkà 4: 1-3) Yàtọ̀ sí àwọn tá a mẹ́nu bà yìí, ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn borí àwọn àṣà àtàwọn ìwà tí Ọlọ́run ò fẹ́, èyí tó ti mọ́ wọn lára.—1 Kọ́r. 6:9-11.
4 Kí Ló Mú Kó Jẹ́ Kánjúkánjú Báyìí: Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá ti là wá lọ́yẹ̀ ohun tí àkókò tá à ń gbé yìí túmọ̀ sí. Àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ lórí bó ṣe máa ṣèdájọ́ ní àwọn ìsọfúnni tó bóde mu tá a gbọ́dọ̀ polongo kárí ayé nínú. (Ìṣí. 14:6, 7) Kristi ń jọba lókè ọ̀run, ilẹ̀ ọba ìsìn èké sì máa tó kàgbákò ìparun àti pé Ìjọba Ọlọ́run ti wà ní sẹpẹ́ láti pa gbogbo ìjọba ayé run. (Dán. 2:44; Ìṣí. 11:15; 17:16) Èyí ló mú un di kánjúkánjú pé káwọn èèyàn dá Ọba tí Ọlọ́run yàn mọ̀, èyí tó ń ṣàkóso lọ́wọ́ báyìí, kí wọ́n bàa lè jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá kí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú orúkọ Jèhófà sì sún wọn láti máa ké pè é. (Sm. 2:11, 12; Róòmù 10:13; Ìṣí. 18:4) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa ṣe ipa tiwa ní kíkún láti rí i pé à ń gbin ìmọ̀ tó máa fún àwọn èèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun sí wọn nínú.