Kọ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Láti Máa Rìn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Fẹ́
1. Bá a bá fẹ́ sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?
1 Ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi pé wọ́n jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2) Béèyàn bá máa jẹ́ Kristẹni tòótọ́, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ délẹ̀délẹ̀ ni. (Òwe 3:5, 6) Nítorí náà, bá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká ṣe kọjá kíkọ́ wọn ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà.—Sm. 25:8, 9.
2. Kí ló lè sún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dẹni tó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́?
2 Kí Wọ́n Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù: Ó sábà máa ń ṣòro fáwọn èèyàn aláìpé láti jẹ́ kí èrò, ìṣesí, ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìwà wọn bá ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ mu! (Róòmù 7:21-23; Éfé. 4:22-24) Àmọ́, ìfẹ́ táwọn ọlọ́kàn tútù ní fún Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ló máa ń sún wọn láti borí ìṣòro yìí. (Jòh. 14:15; 1 Jòh. 5:3) Báwo la ṣe wá lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti nírú ìfẹ́ yìí?
3. Ọ̀nà wo la lè gbà mú káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù?
3 Ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Arákùnrin kan ṣàlàyé pé: “Àwọn èèyàn ò lè nífẹ̀ẹ́ ẹni tí wọn kò mọ̀, nítorí náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo máa ń kọ́ wọn ní orúkọ Ọlọ́run láti inú Bibeli, mo sì máa ń wọ́nà láti tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jèhófà.” Títẹ àwọn àpẹẹrẹ Jésù mọ́ wọn lọ́kàn ni ọ̀nà tó dáa jù lọ láti ṣe èyí. (Jòh. 1:14; 14:9) Bákan náà, lo àpótí àtúnyẹ̀wò tó wà níparí orí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó ṣeyebíye àti ti Ọmọkùnrin rẹ̀.
4. (a) Kí ló máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù ṣòro fún ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fúngbà àkọ́kọ́?
4 Jẹ́ Àwòkọ́ṣe: Níwọ̀n bá a ti jẹ́ olùkọ́ àti afinimọ̀nà, ṣe ló yẹ kí ìwà wa máa fi bó ṣe yẹ kéèyàn rìn lọ́nà Ọlọ́run hàn. (1 Kọ́r. 11:1) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ò mọ bí wọ́n ṣe lè sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àlejò. Nítorí náà, ó máa gba sùúrù àti ọgbọ́n kéèyàn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi ní ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí wọ́n nílò láti lè máa wàásù kí wọ́n sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (2 Kọ́r. 4:13; 1 Tẹs. 2:2) Bó ṣe ń wù wá láti fi àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀nà á jẹ́ ká lè máa wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.
5. Báwo ni jíjẹ́ àwòkọ́ṣe ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fi òfin Ọlọ́run ṣèwà hù?
5 Àpẹẹrẹ tìẹ fúnra ẹ lè jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe nínú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó jẹ́ ti Kristẹni. Bó o bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tí ara rẹ̀ ò yá tàbí tó o kí àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, wọ́n á fojú ara wọn rí ohun tó ń jẹ́ ojúlówó ìfẹ́ ará. (Jòh. 15:12) Bó o bá ń lọ́wọ́ sí mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tàbí tó ò ń ṣe nǹkan kan tó lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, ṣe lò ń kọ́ wọn pé káwọn náà máa ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin wọn. (Jòh. 13:12-15) Bí wọ́n bá rí ọ tó ò ń ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wọ́n á tètè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti fi ‘wíwá Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́.’—Mát. 6:33.
6. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde ríran àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́wọ́ láti sin Jèhófà?
6 Ó gba ìsapá gidigidi kéèyàn tó lè kọ́ àwọn ẹlòmíì ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run débi tí wọ́n á fi di ọmọ ẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n, ayọ̀ ńlá ló máa ń jẹ́ láti rí àwọn ọlọ́kàn tútù tí wọ́n “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́”!—3 Jòh. 4.