Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Mar. 15
“Èyí tó pọ̀ lára wa ló ti mọ bó ṣe máa ń rí lára béèyàn ẹni bá kú. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ ìlérí tó ń tuni nínú yìí rí? [Ka Ìṣe 24:15. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń ṣe kàyéfì pé, Àwọn wo ló máa jíǹde? Ìgbà wo ló máa jẹ́? Ibo ló sì ti máa wáyé? Ìwé ìròyìn yìí sọ bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè náà.”
Ile Iṣọ Apr. 1
“Ọ̀rọ̀ tí gbogbo ayé mọ̀ yìí ló jẹ́ ká mọ bí gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú ṣe ṣe pàtàkì tó. [Ka Mátíù 4:4.] Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣòro fún láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà ti kíyè sí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ní àmọ̀ràn tó wúlò nínú, èyí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.”
Jí! Jan.–Mar.
“Ohun táwọn èèyàn ń rò nípa ọjọ́ ọ̀la ò lóǹkà, àmọ́ àlá tí ò lè ṣẹ lásán lọ̀pọ̀ nínú wọn. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn yìí ṣe ṣàlàyé, Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run ò ní gbà káwọn ìṣòro tó ń pani lẹ́kún yìí máa bá a lọ títí láé. Dandan ni kó mú ìfẹ́ rẹ̀ fún ẹ̀dá ṣẹ.” Ka Aísáyà 55:10, 11.
“Lójúmọ́ tó mọ́ lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ló ka Bíbélì sí ìwé kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò. Àmọ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí rèé. [Ka 2 Tímótì 3:16, 17. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ó dájú pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé àti pé kì í bà á tì tó bá dọ̀ràn ọgbọ́n tó wúlò. Bó o bá wonú Bíbélì, wàá rí àìmọye àmọ̀ràn tó wúlò lórí ìgbésí ayé ìdílé, lórí ìlera àti ẹ̀dùn ọkàn, lórí òwò àtàwọn ọ̀ràn ìgbésí ayé mìíràn.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 22 hàn án.