Ẹ “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo”
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé bí wọ́n ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í láyọ̀. Àmọ́, Jésù sọ̀rọ̀ nípa bí ṣíṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì ṣe lè jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ayọ̀. (Ìṣe 20:35) Ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, . . . kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Máàkù 8:34) Èyí ju pé kéèyàn kàn máa pa àwọn ìgbádùn kan tì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa fi ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ìfẹ́ Jèhófà dípò ká máa ṣe ìfẹ́ tara wa.—Róòmù 14:8; 15:3.
2 Ìwọ wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nítorí “ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù,” Pọ́ọ̀lù jáwọ́ nínú lílépa àwọn nǹkan tó kọ́kọ́ fojú sùn, ó sì wá fi ara rẹ̀ jìn fún ìtẹ̀síwájú àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Fílí. 3:7, 8) Ó ní: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá,” lẹ́nu ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn. (2 Kọ́r. 12:15) Ó tọ́ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Kí ni mò ń lo àkókò mi, okun mi, òye mi àti dúkìá mi fún? Ṣé bí mo ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣe ìfẹ́ inú ara mi ni mo gbájú mọ́ ni àbí bí mo ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà?’
3 Bá A Ṣe Lè Lo Ara Wa Fáwọn Ẹlòmíì: Lọ́dọọdún, ó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí táwa èèyàn Ọlọ́run ń lò láti fi ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Tọmọdé tàgbà ló ní ojúṣe tiẹ̀ nínú ìjọ, ṣíṣe ojúṣe yìí sì ń ṣàǹfààní fáwọn ẹlòmíràn. Kò mọ síbẹ̀ nìkan, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló tún wà tá à ń ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wa tó fi mọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé àti títún àwọn ilé tá à ń lò fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́ ṣe. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ táwọn arákùnrin tó ń sìn nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àti Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ń pèsè kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ìbùkún ńlá ni onírúurú ọ̀nà táwọn arákùnrin yìí gbà ń yọ̀ǹda ara wọn jẹ́ fún ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé!—Sm. 110:3.
4 Àǹfààní tá a lè fi lo ara wa fáwọn ẹlòmíràn lè jẹyọ nígbà tí àjálù tàbí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, a tiẹ̀ lè rí Kristẹni bíi tiwa kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí ìṣírí. (Òwe 17:17) Bá a bá wà lójúfò láti lo ara wa fáwọn ẹlòmíì àti fún ìtẹ̀síwájú àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, a jẹ́ pé àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀lé. (Fílí. 2:5-8) Ǹjẹ́ ká lè máa bá a nìṣó láti lo ara wa fáwọn ẹlòmíràn.