ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/97 ojú ìwé 1
  • Máa Tọ Jésù Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tọ Jésù Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Ẹmi Ifara-ẹni-rubọ Ṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí a Ò Ṣe Ní Wà Láàyè Fún Ara Wa Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ Ni Ẹmi Ifara-Ẹni-Rubọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 5/97 ojú ìwé 1

Máa Tọ Jésù Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo

1 Ní àkókò kan, Jésù wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mát. 16:24) Dájúdájú, a fẹ́ láti fi ìtara dáhùn pa dà sí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí àpólà ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan nínú ìkésíni rẹ̀ ní nínú.

2 “Kí Ó Sẹ́ Níní Ara Rẹ̀”: Nígbà tí a ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sẹ́ níní ara wa. Ìtumọ̀ pàtàkì ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “sẹ́ níní” ni “láti sọ pé rárá.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé a fínnúfíndọ̀ yááfì àwọn góńgó ìlépa wa, ìfẹ́ ọkàn wa, ìgbádùn, àti fàájì onímọtara-ẹni-nìkan—ní pípinnu láti mú inú Jèhófà dùn títí ayérayé.—Róòm. 14:8; 15:3.

3 ‘Kí Ó Gbé Òpó Igi Oró Rẹ̀’: Ìgbésí ayé Kristẹni jẹ́ ìgbésí ayé gbígbé òpó igi oró ti iṣẹ́ ìsìn onírùúbọ sí Jèhófà. Ọ̀nà kan tí a lè gbà fi ẹ̀mí onífara-ẹni-rúbọ hàn ni nípa lílo ara ẹni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Níbi tí a ṣì bá a dé lọ́dún yìí, ọ̀pọ̀ akéde ti ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bóyá o wà lára wọn, tí o sì lè jẹ́rìí sí i pé àwọn ìbùkún tí o rí ju àwọn ohun tí o yááfì lọ. Àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ti ṣètò lóòrèkóòrè láti lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí akéde ìjọ. Nítorí ìyẹn, àwọn ìjọ kan ń ṣètò ìpàdé wọn fún iṣẹ́ ìsìn pápá sí ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣáájúu bí wọ́n ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ akéde mọrírì àkókò tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i yìí fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn kan tún ti ṣe àṣeyọrí títayọ lọ́lá nígbà tí wọ́n pinnu láti sọ̀rọ̀ ní ‘kìkì ilé kan sí i ní àfikún’ tàbí láti ṣiṣẹ́ ‘fún kìkì ìṣẹ́jú díẹ̀ sí i.’

4 Ọ̀nà míràn tí a gbà ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn jẹ́ nípa gbígbé góńgó ara ẹni kalẹ̀. Nípa ìwéwèé tí wọ́n fẹ̀sọ̀ ṣe, àti nípa ṣíṣàtúnṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ, àwọn kan ti di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn mìíràn láti ṣètò àlámọ̀rí wọn kí wọ́n lè mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tàbí fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àwọn kan ti ṣí lọ sí àgbègbè kan tí àìní títóbi jù ti wà fún àwọn akéde Ìjọba.

5 “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo”: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nírìírí ọ̀pọ̀ àdánwò, ìtara àti ìfaradà rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún wọn níṣìírí. (Jòh. 4:34) Wíwà níbẹ̀ rẹ̀ àti ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sọ ẹ̀mí wọn dọ̀tun. Ìdí nìyẹn tí àwọn tí wọ́n tọ̀ ọ́ lẹ́yìn fi fi ojúlówó ìdùnnú hàn. (Mát. 11:29) Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú fún ẹnì kíní kejì níṣìírí láti fara dà nínú iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì jù lọ náà ti wíwàásù Ìjọba àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.

6 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi ìtara dáhùn pa dà sí ìkésíni Jésù láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nígbà gbogbo nípa mímú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ dàgbà. Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ní ìdùnnú ńláǹlà nísinsìnyí, a sì lè máa fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún títóbi jù ní ọjọ́ ọ̀la pàápàá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́