Ẹ Ni Ẹmi Ifara-Ẹni-Rubọ
ROLFa jẹ́ ẹni-a-gbà-síṣẹ́ ti a mọyi rẹ̀ daradara. Nigba ti o pinnu lati gba iṣẹ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ki o baa lè mu ìpín rẹ̀ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni gbooro si, agbanisíṣẹ́ rẹ̀ fọwọsowọpọ laijanpata. Fun idi yẹn ó ṣeeṣe fun Rolf lati gbadun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna fun ọpọ ọdun. Bi o ti wu ki o ri, ni ọjọ kan, ipo iṣẹ naa yipada. Rolf ti fi araarẹ han bii adáńgájíá lẹnu iṣẹ rẹ̀ debi pe a fi ipo oluṣabojuto ọja rírà fun ilé iṣẹ naa lọ̀ ọ́. Iṣẹ naa wá pẹlu owo-iṣẹ ti ń wọniloju kan ati awọn ireti rere fun itẹsiwaju siwaju sii. Bi o ti wu ki o ri, iṣẹ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ki yoo lè ṣeeṣe mọ́.
Rolf ni aya kan ati ọmọ meji lati bojuto, àlékún owo naa ìbá sì ti wulo gan-an. Sibẹ, ó kọ ifilọni naa silẹ ó sì kọwe beere fun iṣẹ miiran, ọ̀kan ti yoo yọnda rẹ̀ lati kunju iṣẹ-aigbọdọmaṣe tẹmi ati ti iṣunna-owo rẹ̀. Agbanisíṣẹ́ Rolf ni ipinnu yii yà lẹnu. Ni mímọ̀ daju pe ifilọni owo-iṣẹ giga sii kan paapaa yoo jasi asán, ọga rẹ̀ pari ọrọ pe: “Mo lè ri i pe emi kò lè farawe igbagbọ fifidimulẹ ṣinṣin rẹ.”
Bẹẹni, Rolf ni igbagbọ fifidimulẹ ṣinṣin. Ṣugbọn oun tun ni animọ miiran—ẹmi ifara-ẹni-rubọ. Iru ẹmi kan bẹẹ ṣọwọn ninu ayé ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ wa. Ṣugbọn ó lè ṣamọna si ọna igbesi-aye kan ti o ṣanfaani ti ó sì ń tẹnilọrun. Ki ni ẹmi ifara-ẹni-rubọ? Ki ni ó ni ninu? Ki ni a sì gbọdọ ṣe lati pa á mọ?
Ohun Kan Ti Bibeli Beere Fun
Lati rubọ tumọsi lati dáwọ́ nini tabi fi ohun kan ti o ṣeyebiye lélẹ̀. Irubọ ti jẹ apakan ijọsin mimọgaara lati igba ti ẹlẹ́rìí oluṣotitọ akọkọ naa, Ebẹli, ti pese “akọbi ẹran-ọsin” ninu irubọ si Ọlọrun. (Jẹnẹsisi 4:4) Awọn ọkunrin igbagbọ, iru bii Noa ati Jakọbu, ṣe bakan naa pẹlu. (Jẹnẹsisi 8:20; 31:54) Awọn irubọ ẹran tun jẹ́ ìhà ṣiṣepataki kan ninu Ofin Mose. (Lefitiku 1:2-4) Bi o ti wu ki o ri, awọn olujọsin ni a ṣileti labẹ Ofin yẹn lati fi ohun didara julọ wọn rubọ. A kò yọnda fun wọn lati mú ẹran alábùkù ara eyikeyii wá fun irubọ. (Lefitiku 22:19, 20; Deutaronomi 15:21) Nigba ti awọn Isirẹli apẹhinda tàpá si ofin yii, Ọlọrun bá wọn wí, ni wiwi pe: “Bi ẹyin bá sì fi amúkùn-ún ati olókùnrùn rubọ, ibi kọ́ eyiini? Mu un tọ baalẹ rẹ lọ nisinsinyi; inu rẹ̀ yoo ha dun si ọ, tabi yoo ha kà ọ́ si? . . . Emi yoo ha gba eyi lọwọ yin?”—Malaki 1:8, 13.
Ilana ẹbọ rírú ni a gbé wọnu ijọsin Kristẹni. Bi o ti wu ki o ri, niwọn bi Kristi ti san iye irapada kikun naa, awọn irubọ ẹran ni kò nitẹẹwọgba lọdọ Ọlọrun mọ. Nitori naa, ki ni awọn Kristẹni lè fi rubọ lọna itẹwọgba? Pọọlu kọwe ni Roomu 12:1 pe: “Nitori naa mo fi ìyọ́nú Ọlọrun bẹ̀ yin, ará, ki ẹyin ki o fi araayin fun Ọlọrun ni ẹbọ ààyè, mímọ́, itẹwọgba, eyi ni iṣẹ-isin yin ti o tọna.” Iru iyipada yiyanilẹnu wo ni eyi jẹ́! Dipo fifi awọn ara oku ẹran rubọ, awọn Kristẹni ni wọn nilati fi araawọn ti ó walaaye—awọn okun wọn, ohun-ìní, ati agbara-iṣe rubọ. Ati gẹgẹ bi o ti ri ni Isirẹli, Jehofa kò ni tẹwọgba awọn irubọ “amúkùn-ún,” tabi alaifitọkantọkanṣe. Oun fi dandan beere pe ki awọn olujọsin oun fun oun ni ohun didara julọ wọn, pe ki wọn ṣiṣẹsin oun pẹlu gbogbo ọkan-aya, ọkàn, ero-inu, ati okun wọn.—Maaku 12:30.
Ẹmi ifara-ẹni-rubọ nipa bayii wémọ́ oun pupọ ju wiwulẹ fi ara ẹni fun itolẹsẹẹsẹ awọn ipade ati igbokegbodo ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni. Ó tumọ si ipinnu lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun laika ohunkohun ti ó náni si. Ó tumọsi wíwà ni sẹpẹ lati jiya awọn inira ati airọgbọ. “Bi ẹnikẹni bá fẹ tẹle mi,” ni Jesu wí, “jẹ ki o sẹ́ araarẹ ki o si gbe òpó igi idaloro rẹ̀ ki o si maa tọ̀ mi lẹhin nigba gbogbo.” (Matiu 16:24, NW) Kristẹni kan kii fi ilepa ara-ẹni tabi awọn gongo ohun ti ara ṣe idaniyan rẹ̀ pataki. Igbesi-aye rẹ̀ rọ̀ yika lilepa Ijọba Ọlọrun ati ododo Rẹ̀ lakọọkọ. (Matiu 6:33) Bi o ba pọndandan, oun ṣetan lati “gbé òpó igi idaloro rẹ̀,” jiya inunibini, itiju, tabi iku paapaa!
Awọn Ibukun Ti Wọn Ń Wá Lati Inu Ifara-Ẹni-Rubọ
Ni didojukọ iru awọn ohun ṣiṣeeṣe ti o wuwo bẹẹ, ẹnikan lè ṣe kayefi lọna ti ẹ̀dá bi ifara-ẹni-rubọ bá tóye fun un. Fun awọn wọnni ti wọn nifẹẹ Jehofa Ọlọrun ti wọn sì daniyan lati ri ki a bọla fun orukọ rẹ̀, ó toye dajudaju. (Matiu 22:37) Gbe apẹẹrẹ pípé ti Jesu Kristi fi lélẹ̀ yẹwo. Ṣaaju wíwá si ilẹ-aye, oun gbadun ipo giga kan ni ọrun gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi kan. Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi ó ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, oun lépa ‘kii ṣe ifẹ-inu oun fúnraarẹ̀, bikoṣe ifẹ-inu Ọlọrun, ẹni ti ó rán an.’ (Johanu 5:30) Nitori naa ó fi imuratan “sọ araarẹ dòfo ó sì mu aworan irisi ẹrú, ó sì wá wà ni jijọ awọn eniyan. Ju eyiini lọ, nigba ti o ri araarẹ ni àwọ̀ ẹ̀dá bi eniyan, ó rẹ araarẹ silẹ ó sì di onigbọran titi dé oju iku, bẹẹ ni, iku lori òpó igi idaloro.”—Filipi 2:7, 8 NW.
Iru awọn irubọ bẹẹ kò jasi alaileso. Nitori pe Jesu wà ni imuratan lati “fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ nitori awọn ọrẹ rẹ̀,” oun lè san iye owo irapada naa, ti yoo mu ki o ṣeeṣe fun awọn eniyan alaipe lati jere yala aileku ninu awọn ọrun, tabi ìyè ainipẹkun lori ilẹ-aye. (Johanu 3:16; 15:13; 1 Johanu 2:2) Nipa pipa iwatitọ rẹ̀ mọ lọna pipe, ó mu ki orukọ Jehofa di eyi ti a yin gidigidi. (Owe 27:11) Abálájọ ti Jehofa fi bukun fun ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ rẹ̀! “Ọlọrun . . . gbé e ga si ipo gigalọlaju kan ó sì fi inurere fun un ni orukọ ti o lékè gbogbo orukọ miiran.”—Filipi 2:9, NW.
Dajudaju, Jesu ni Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo ti Ọlọrun. Ọlọrun ha tun san ẹsan rere fun awọn miiran ti wọn ṣe awọn irubọ fun un bi? Bẹẹni, eyi ni a sì fihan nipa ọpọlọpọ apẹẹrẹ ni awọn akoko igbaani ati ti ode oni. Gbe akọsilẹ Bibeli ti Ruutu ara Moabu yẹwo. Oun ni ó jọ bii pe o kẹkọọ nipa Jehofa nipasẹ ọkọ rẹ̀ ara Isirẹli. Lẹhin ti [ọkọ] rẹ̀ kú, oun nilati ṣe ipinnu kan. Oun yoo ha wà ni ilẹ abọriṣa ti a ti bi i, tabi yoo ha rinrin-ajo lọ si Ilẹ Ileri pẹlu Naomi, ìyakọ rẹ̀ arugbo? Ruutu yan lati ṣe eyi ti ó kẹhin, bi o tilẹ jẹ pe ó tumọ si fifi ibakẹgbẹ pẹlu awọn obi rẹ̀ ati boya ireti títún igbeyawo ṣe rubọ. Laika eyiini sí, Ruutu ti mọ Jehofa, ifẹ lati jọsin rẹ̀ laaarin awọn eniyan rẹ̀ ti ó yan sì sun [Ruutu] lati dirọ pẹkipẹki mọ Naomi.
Njẹ a san ẹsan rere fun Ruutu fun iru ifara-ẹni-rubọ bẹẹ bi? Dajudaju a san ẹsan rere fun un! Laipẹ, ẹnikan ti ó ní ilẹ̀ ti a ń pe ni Boasi fi ṣe aya, Ruutu sì di iya ọmọkunrin kan ti a pe ni Obẹdi, eyi ti ó sọ ọ di ìyáńlá Jesu Kristi.—Matiu 1:5, 16.
Awọn ibukun ni awọn iranṣẹ olufara-ẹni-rubọ fun Ọlọrun ní akoko ode oni ti gbadun bakan naa. Fun apẹẹrẹ, ni 1923, William R. Brown, ti a mọ daradara si “Bible” Brown, fi ilu rẹ̀ ni West Indies silẹ lati ṣaaju iṣẹ iwaasu ni Iwọ-oorun Africa. Awọn ti ó tẹle e ni aya ati ọmọbinrin rẹ̀. Oun lẹhin-ọ-rẹhin ṣí lọ si Nigeria, nibi ti iṣẹ iwaasu naa ti ṣẹṣẹ ń bẹrẹ lati mu eso jade. Papọ pẹlu ara America aláwọ̀ dudu kan ti ń jẹ́ Vincent Samuels ati Ẹlẹ́rìí ara West Indies miiran ti ń jẹ́ Claude Brown, “Bible” Brown kó ipa pataki kan ninu awọn ipo akọkọ ti iṣẹ ni Iwọ-oorun Africa.
Lonii awọn akede ti iye wọn ju 187,000 ń ṣiṣẹsin ni awọn ipinlẹ Sierra Leone, Liberia, Ghana, ati Nigeria, nibi ti “Bible” Brown ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti ṣeranlọwọ ni idagbasoke wọn. Ṣaaju iku rẹ̀ ni 1967, “Bible” Brown sọ pe: “Ayọ wo ni ó jẹ́ lati ri awọn ọkunrin ati obinrin ti wọn ń di onigbọran si ihinrere Ijọba Ọlọrun!” Bẹẹni, oun ni a bukun ni jìngbìnnì fun ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ rẹ̀.
Awọn Ọna Lati Jẹ́ Olufara-ẹni-rubọ
Ki ni awọn ọ̀nà diẹ ti a lè gbà fi ẹmi kan naa han lonii? Ọ̀kan ni lati ni ipin deedee lọsọọsẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile. (Iṣe 20:20) Ṣiṣe bẹẹ, ni pataki lẹhin ọsẹ ti ó ti rẹni lẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ, lè má rọrun. Ó lè beere fun ìbára-ẹni-wí, ati itolẹsẹẹsẹ rere. Ṣugbọn ayọ tí ó wà nibẹ kọja airọgbọ eyikeyii ti a ti lè jiya rẹ̀. Eeṣe, iwọ lè ni anfaani ríran ẹnikan lọwọ lati di “iwe Kristi . . . kii ṣe eyi ti a fi tàdáwà kọ, bikoṣe ẹmi Ọlọrun alaaye; kii ṣe ninu ọpọ́n okuta, bikoṣe ninu ọpọ́n ọkàn ẹran.”—2 Kọrinti 3:3.
Ni fifi tiṣọratiṣọra “ra ìgbà pada,” boya lati inu iṣẹ ounjẹ oojọ tabi eré-ìnàjú, awọn kan ti mu ipin wọn ninu iṣẹ iwaasu pọ sii. (Efesu 5:16) Ọpọlọpọ ṣeto itolẹsẹẹsẹ wọn ki wọn baà lè gbadun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna oluranlọwọ ó keretan lẹẹkan lọdun. Ó ṣeeṣe fun awọn miiran lati ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ laidawọduro tabi ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee. Irubọ miiran lati gbeyẹwo ni ti ṣiṣilọ si agbegbe ti o nilo awọn akede Ijọba pupọ sii. Eyi niye igba ń mu awọn iyipada patapata ninu aṣa igbesi-aye lọwọ, fifarada awọn airọgbọ, mimu ara bá awọn aṣa ibilẹ ati aṣa titun mu. Ṣugbọn awọn ibukun ti ninipin-in kikun ninu ríran awọn ẹlomiran lọwọ lati jere ìyè mu ki iru awọn irubọ bẹẹ yẹ fun isapa.
John Cutforth ti a bí ni Canada ṣàwárí eyi funraarẹ. Lẹhin ikẹkọọjade rẹ̀ kuro ni Watchtower Bible School of Gilead, a pinṣẹ yan fun un gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ Ọlọrun si Australia. “Ibi jijinna sí ile wo ni iyẹn jẹ!” ni Arakunrin Cutforth ranti. “Emi yoo ha lè pada si Canada lae lati ri awọn obi ati ọrẹ mi lẹẹkan sii ṣaaju Amagẹdọni bi? Ọna kanṣoṣo lati ṣàwárí eyi ni lati lọ.” Arakunrin Cutforth lọ, kò si kábàámọ̀ awọn irubọ ti ó ṣe. Ni awọn ọdun lẹhinwa igba naa ó ṣe òléwájú iṣẹ ijẹrii ni Papua New Guinea, nibi ti oun ti ń ṣiṣẹsin pẹlu itara sibẹ, lẹhin ti o ti lo 50 ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko kikun. Oun sọ nigba kan ri pe: “Wíwá ọna nigba gbogbo lati tẹle idari Jehofa, titẹwọgba iṣẹ ayanfunni yoowu ti ó ri pe o yẹ lati fifunni, ń mu ayọ, idunnu, itẹlọrun, ati ainiye awọn ọrẹ wá.”
Dajudaju, awọn ipo iru bii ilera, iṣunna owo, ati awọn aigbọdọmaṣe idile lè pààlà si ohun ti o lè ṣe; kii ṣe gbogbo eniyan ni o lè ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ati ojihin-iṣẹ Ọlọrun. Sibẹ, jẹ́ onipinnu lati ni ipin kikun ninu awọn ipade ati iṣẹ-isin pápá gẹgẹ bi o bá ti ṣeeṣe tó, lai yọnda awọn airọgbọ ti kò tó nǹkan, iru bii ipo oju ọjọ ti kò dara, lati dá ọ duro. (Heberu 10:24, 25) Ó tun lè ṣeeṣe fun ọ lati fi akoko pupọ sii rubọ fun idakẹkọọ Ọrọ Ọlọrun. Awọn idile kan ń ṣe bẹẹ nipa didin akoko ti wọn ń lo fun wiwo awọn itolẹsẹẹsẹ ori tẹlifiṣọn kù, boya nipa níní alẹ́ “kò si tẹlifisọn” kan lọsẹ kan tabi ki o má sí tẹlifisọn rara. Nipa wiwa akoko fun idakẹkọọ, “ẹbọ iyin” naa nipa eyi ti iwọ “jẹ́wọ́ orukọ rẹ̀” ní awọn ipade ati ninu iṣẹ-isin papa ni o ṣeeṣe julọ ki o jẹ́ irubọ kan ti ìjójúlówó rẹ̀ ga.—Heberu 13:15.
Ranti, iṣẹ iwaasu naa ti wà ninu ipele rẹ̀ ti ó kẹhin. Laipẹ Ọlọrun yoo mu idajọ wá sori ayé oniwọra ati akẹra-ẹni-bajẹ yii. (Sefanaya 2:3) Lati pa ojurere Ọlọrun mọ, awa kò lè jẹ́ adára-ẹni-sí. A gbọdọ ‘gbe araawa kalẹ bii ẹbọ aaye, mímọ́, ti o ṣetẹwọgba fun Ọlọrun.’ (Roomu 12:1) Iru ẹmi kan bẹẹ yoo mu ayọ titobi ati itẹlọrun wá. Yoo ran wa lọwọ lati ri ayọ titobi ju ninu iṣẹ-isin wa. Yoo sì mu ọkan-aya Jehofa yọ̀!—Owe 27:11.
Nitori naa pa ẹmi ifara-ẹni-rubọ mọ! Maṣe fasẹhin lati fi araarẹ sinu airọgbọ lati ran awọn ẹlomiran lọwọ ati ni itilẹhin fun awọn ire Ijọba. Pọọlu rọni pe: “Ati maa ṣoore oun ati maa pinfunni ẹ maṣe gbagbe: nitori iru ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dun si jọjọ.”—Heberu 13:16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orukọ ni a ti yipada.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Wíwá akoko fun idakẹkọọ ati iṣẹ-isin papa lè mu awọn irubọ lọwọ, ṣugbọn ó lérè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
W. R. Brown ati John Cutforth ni a bukun fun jìngbìnnì nitori ipa-ọna ifara-ẹni-rubọ wọn