ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 2/1 ojú ìwé 24
  • ‘Kíkórè’ Ni Venezuela

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Kíkórè’ Ni Venezuela
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “A Ti Ṣe Ìpínlẹ̀ Wa Lọ́pọ̀ Ìgbà!”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àwọn Pápá Ti Funfun fún Kíkórè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ẹ Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Tí Ń fi Tayọ̀tayọ̀ Kórè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 2/1 ojú ìwé 24

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

‘Kíkórè’ Ni Venezuela

Ni akoko kan Jesu fi iṣẹ iwaasu wé ìkórè ọdọọdun. (Matiu 9:36-38) Ọga ìkórè ni Jehofa Ọlọrun, ìkórè naa sì pọ nitootọ yika ayé. Eyi ní ipinlẹ ti a kii saba ṣe ni Venezuela ninu.

Ẹka ọfiisi Watch Tower Society ti Venezuela rohin ohun ti ó ṣẹlẹ nigba ti awujọ awọn Ẹlẹ́rìí kan ṣe iṣẹ ni ipinlẹ Sabana Grande, Ipinlẹ Guárico. Awọn Ẹlẹ́rìí naa sọ pe: “Ile ti awa nilati gbe inu rẹ jẹ́ ibi ti o dara fun awọn ipade, nitori naa lọgan a bẹrẹ sii ké si awọn eniyan si ipade nibẹ. Awọn eniyan naa kò mọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o tilẹ jẹ pe awọn awujọ ṣọọṣi ajihinrere mẹrin ni o wà ninu ilu, awọn eniyan ní iharagaga lati kẹkọọ lati inu Bibeli.

“A ṣiṣẹ fun wakati mẹta ni owurọ ati fun wakati mẹta ni ọsan, ni lilọ lati ile de ile ati kikesi awọn eniyan si ipade kan ni alẹ ti o tẹle e. A kò ni awọn aga, nitori naa a sọ fun wọn pe ki wọn gbe aga tiwọn funraawọn wa. Nigba ti akoko fẹrẹẹ tó fun ipade lati bẹrẹ, awọn eniyan bẹrẹ sii de, ẹnikọọkan pẹlu aga kan. Nigba ti ipade naa pari, a sọ fun wọn pe awa yoo fẹ lati kọ orukọ awọn wọnni ti wọn fẹ lati gba ikẹkọọ Bibeli inu ile lọfẹẹ silẹ. Gbogbo awọn eniyan 29 ti wọn wá fẹ ki orukọ wọn wà ninu iwe naa.

“Bi a ti ń ti ilẹkun lẹhin alejo ti ó kẹhin, a ṣakiyesi awọn ọkunrin mẹta ni igun ile naa. Ni nǹkan bii agogo mẹsan-an, a ṣetan lati jokoo lati jẹun nigba ti wọn kan ilẹkun. Wọn beere awọn ibeere iru bii: ‘Ki ni iwaasu yii ti ẹyin ń ṣe ninu ilu yii? Fun idi wo ni ẹ ṣe ṣe ipade kan nihin-in ni alẹ yii?’

“A beere bi a bá ti tapa si ofin eyikeyii. Wọn dahun pe rara wọn sì sọ pe awọn jẹ́ pasitọ mẹta ninu awọn ṣọọṣi ajihinrere ti ilu naa. Idaamu bá wọn nitori pe awọn ṣọọṣi wọn ṣófo ni irọlẹ yẹn. A késí wọn wọle a sì ṣalaye iṣẹ wa. A tun fi iwe ikẹkọọ diẹ silẹ fun wọn a sì sọ fun wọn pe ki wọn pada wá ni ọjọ Thursday ti o tẹle e.

“Ni ọjọ Thursday ti o tẹle e awọn pasitọ naa wa tí awọn eniyan 22 miiran ti wọn fẹ́ lati gbọ ohun ti a ni lati sọ sì tẹle wọn. Awọn pasitọ naa lero pe, nitori pe a jẹ́ obinrin, awa kò ni lè dọgba pẹlu wọn ninu ijiroro. Bi o ti wu ki o ri, ipade naa ṣaṣeyọrisirere ni oju iwoye wa. Ni ipari a ṣalaye pe a ń ṣe akọsilẹ orukọ awọn wọnni ti wọn fẹ́ lati kẹkọọ sii lati inu Bibeli. Pupọ alabaakẹgbẹ awọn pasitọ naa fẹ ki a fi orukọ wọn kun akọsilẹ naa, awọn kan sì tilẹ sọ pe awọn fẹ lati ba wa jade ninu iṣẹ iwaasu!

“A ṣalaye pe wọn yoo nilo imọ Bibeli ati idalẹkọọ pupọ sii ṣaaju ki wọn tó lè darapọ pẹlu wa ninu iṣẹ ijẹrii. Lojoojumọ awọn eniyan ń wa si ile naa, ni sisọ fun wa lati ṣalaye Bibeli fun wọn. Nigba miiran, ti a ba ti sọrọ titi di ìgbà ti ilẹ ti ṣu gidigidi, a nilati sọ fun wọn lati lọ si ile. Nigba ti a nilati fi ipinlẹ naa silẹ nikẹhin, inu wọn bajẹ gidigidi wọn sì sọ fun wa pe nigba ti a ba pada dé, awọn yoo bá wa lọ ninu iṣẹ iwaasu. Wọn ṣeleri pe nigba naa awọn yoo ti ni itẹsiwaju ti a beere fun naa.”

Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí naa fi ipinlẹ yẹn silẹ, awọn eniyan 40 ni wọn wà ti wọn fẹ́ lati kẹkọọ Bibeli. Orukọ awọn eniyan olufifẹhan wọnyi ni a fifun ijọ ti o sunmọtosi julọ, eyi ti o wà ni nǹkan ti o jinna to 30 ibusọ. Lẹhinwa ìgbà naa, awọn Ẹlẹ́rìí diẹ lati inu ilu miiran ti ṣí lọ sinu ilu yii, awujọ awọn oniwaasu ihinrere onitara kan ni a sì ti dá silẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́