Ǹjẹ́ O Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ?
1 Ó yẹ kí ìmọrírì fún ohun tí Jésù Kristi ṣe nítorí aráyé láìmọtara rẹ̀ nìkan sún gbogbo wa láti lo òye, agbára, àti okun wa lọ́nà ìfara-ẹni-rúbọ. Ìwé Mímọ́ pàrọwà pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.” (Róòmù 12:1) Ṣíṣàyẹ̀wò ara rẹ látìgbàdégbà yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá o ń fi irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ hàn dáadáa bí ipò rẹ ti gbà ọ́ láyè tó.
2 Nínú Wíwá Ìmọ̀ Bíbélì: Ǹjẹ́ o ti ṣètò àkókò fún dídá ka Bíbélì, àti dídá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé? Ṣe o ń tẹ̀ lé ètò yẹn? Ṣé àṣà rẹ ni láti máa múra sílẹ̀ dáadáa fún àwọn ìpàdé ìjọ? Bó bá jẹ́ olórí ìdílé ni ẹ, ṣé o máa ń bá ìdílé rẹ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé? Ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí lè béèrè pé kí o yááfì àwọn àkókò tí o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n tàbí àkókò tí o ń lò nídìí kọ̀ǹpútà àti àkókò tí o máa fi ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn. Ṣùgbọ́n o, nǹkan tí o ní láti yááfì kò pọ̀ rárá bóo bá rántí pé àkókò tí o bá lò nídìí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun!—Jòh. 17:3.
3 Nínú Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ: Ìgbà tó dáa jù láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nípa bí èèyàn ṣe ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn ni ìgbà ọmọ ọwọ́. Kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò wà fún eré, àkókò iṣẹ́ àti àkókò ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú. (Éfé. 6:4) Fún wọn ní iṣẹ́ tó wúlò ṣe láyìíká ilé. Ṣètò láti jẹ́ kí wọ́n máa bá ẹ jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé. Bóo ti ń fún wọn nítọ̀ọ́ni lọ́rọ̀ ẹnu, bẹ́ẹ̀ náà ni kóo máa fi àpẹẹrẹ rere tìẹ tì í lẹ́yìn.
4 Nínú Ìgbòkègbodò Ìjọ: Ìjọ máa ń lárinrin nígbà tí gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀ bá ń fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan láti ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. (Héb. 13:16) Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ lo àkókò tó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? Ǹjẹ́ o lè yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ń ṣàìsàn tàbí láti ran àgbàlagbà lọ́wọ́, bóyá kóo ṣèrànwọ́ láti gbé wọn wá sí ìpàdé?
5 Ṣáájú kí Jésù tó ṣe ìrúbọ tó kẹ́yìn nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n gbájú mọ́ àwọn ire Ìjọba náà, kí wọ́n si fi àwọn ohun yòókù nínú ìgbésí ayé sí ipò kejì. (Mát. 6:33) Lílépa irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ yóò fún wa ní ayọ̀ ńláǹlà bí a ṣe ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀.